Yorùbá: Regular

Updated ? hours ago # views See on DCS

Mark

Chapter 2

1 Nígbàtí Ó padà sí Kápánámù lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ó di mímọ̀ wípé Ó wà nínú ilé. 2 Ọ̀pọ̀lọọpọ̀ sì péjọ níbẹ̀ tóbẹ̀ tí kò fi sí ààyè mọ́, kò sí lẹ́nu ìlẹ̀kùn pẹ̀lú, Jésù sì bá wọn sọ ọ̀rọ̀ náà. 3 Nígbànáà ni àwọn ọkùnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ. wọ́n gbe ọkùnrin arọ kan; ènìyàn mẹ́rin ni ó gbé e. 4 Nígbàtí wọ́n kò sì le dé ọ̀dọ̀ rẹ nítorí ọ̀pọ́ ènìyàn, wọ́n sí òrùlé ibi tí Jésù wa, lẹ́yìn èyí ni wọ́n rí ààyè, wọ́n sì sọ ibùsùn tí ọkùnrin tí arọ náà sùn sí. 5 Jésù rí ìgbàgbọ́ wọn, Ó sì wí fún ọkùnrin arọ náà pé, "Ọmọkùnrin, a fi gbogbo ẹ̀sẹ̀ rẹ jìn ọ́" 6 Àwọn akọ̀wé sì joko síbẹ̀, wọ́n sì nrò nínú ọkàn wọn: 7 "Bawo ni ọkùnrin yi ti nsọ̀rọ̀ bayi? O nsọ̀rọ̀ òdì! Tani ẹni náà tí ó le fi ẹ̀sẹ̀ jìn bíkòse Ọlọ́run nìkan?" 8 Lójú ẹsẹ́ Jésù mọ ohun tí wọn nrò láàrin ara wọn nínú ọkàn rẹ. Ó wí fún wọn, "Kílódé tí ẹ̀yín fi nro èyí nínú ọkàn yin?" 9 Èwo ni ó rorùn jù láti wí fún ọkùnrin tí arọ náà, 'A dárí gbogbo ẹ̀sẹ̀ rẹ jìn ọ́' tàbí lati wípé 'Dìde, gbé ibùsùn rẹ kí o sì ma rìn?' 10 Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó le mọ̀ wípé Ọmọ ènìyàn ní àsẹ ní ayé lati dárí ẹ̀sẹ̀ jìn" Ó wí fún ẹnití ó rọ náà, 11 "mo wí fún ọ, dìde, gbé ení rẹ, kí o sì ma lọ sí ilé rẹ." 12 Ó dìde lójú ẹsẹ́, ó sì gbé ení rẹ, ó sì jáde kúrò ninú ilé náà lójú gbogbo ènìyàn, tóbẹ̀ tí ẹnu sì ya gbogbo wọn, tí wọ́n sì fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì wípé, "A kò rí irú èyí rí rárá." 13 Ó sì tún jáde lẹ́ba omi adágún kan, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, Ó sì kọ́ wọn. 14 Bí Ó sì ti nkọjá lọ, Ó rí Lefi ọmọ Álféusì ti o joko ni àgọ́ agbowó òde, Ó sì wí fún un pé, "Tọ̀ mí lẹ́yìn." Ó dìde, ó sì tọ lẹ́yìn. 15 Jésù si njẹun nínú ilé Lefi àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́sẹ, wọn ba a jẹun pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí wà níbẹ̀, wọ́n si ntọ lẹ́yìn. 16 Nígbàtí àwọn akọ̀wé, ti wọn jẹ́ Farisí, rí tí Jésù njẹun pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sẹ̀ àti àwọn agbowó òde, wọ́n wí fún àwon ọmọ ẹ̀yìn rẹ pe, "Kíló sẹlẹ̀ tí O nfi bá àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́sẹ̀ jẹun?" 17 Nígbàtí Jésù gbọ́ ọ̀rọ̀ yí Ó wí fún wọn pe, "Àwọn ènìyàn tí ara wọn ya kò wá onísègùn; àwọn tí ara wọn kò yá ni wọ́n nílò rẹ. Èmi kò wá lati pe àwọn olododo bíkòse àwọn ẹlẹ́sẹ̀." 18 Ó sì se, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn ti Farisí ngba àwẹ̀. Àwọn ènìyàn kan wá, wọ́n sì wí fún pe, "Kíló dé tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn ti Farisí fi ngbawẹ, sùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yín rẹ ko gbàwẹ̀?" 19 Jésù sí wí fún wọn pé, "Sé ó seése kí àwọn tì ó wá sí ibi ìgbéyàwó ma gbàwẹ̀ nígbàtí ọkọ ìyàwó sì wà pẹ̀lú wọn?" Níwọ̀n ìgbàtí wọn bá sì ní ọkọ ìyàwó larin wọn, kò seése fún wọn lati gbàwẹ̀. 20 Sùgbọ́n ọjọ́ nbọ nígbàtí a o mu ọkọ ìyàwó kúrò lọ́dọ̀ wọn, nígbàyí, wọn yio gbàwẹ̀. 21 Kòsí enìkan tí nran aṣọ titun mọ́ ẹwu tí ó ti gbó, bíbẹ́ẹ̀kọ́, aṣọ titun tí a rán yio ya kúrò lára ti àtijọ́, yio si ya ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. 22 Kòsí ẹnìkan tí nfi wáìnì titun sínú awọ wáìnì àtijọ́, bíkòsebẹ wáìnì náà yio bẹ́ awọ ti wáìnì àti awọ wáìnì yio sì sègbé pọ̀. Dípòo bẹ́ẹ̀, fi wáìnì titun sínú awọ wáìnì titun." 23 Ní ọjọ́ ìsinmi, Jésù nkọjá larin àwọn oko ọkà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ si nre orí ọkà. 24 Àwọn Farisí sì wí fún pe, "Kíyèsíi, kí ni ó dé tí wọn nfi se èyí tí kò bá òfin mu ní ọjọ́ ìsinmi?" 25 Ó sì wí fun wọn pé, "Ẹ̀yin kò tí ka ohun tí Dáfídì se nígbàtí ó se aálaìní tí ebí sì npa á,- oun pẹ̀lú àwọn okùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ- 26 bí ó ti wọ ilé Ọlọ́run nígbàtí Ábíátárì nse olú àlùfáà, ó sì jẹ àkàrà pẹpẹ, èyí tí kò bá òfin mu fún ẹnikẹ́ni láti jẹ àfi àwọn àlùfáà, ó sì tún fi fún àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀.?" 27 Jésù wípé, "Ọjọ́ ìsinmi wà fún ènìyàn, kìí se ènìyàn fún ọjọ́ ìsinmi." 28 Nítorínáà, Ọmọ Ènìyàn ni Olúwa, àní ti ọjọ́ ìsinmi pẹ̀lu.

Chapter 3

1 Lẹ́ẹ̀kan si Jésù rìn lọ sínú sínágọ́gù ọkùnrin kan sí wà níbẹ̀ tí apá rẹ rọ 2 Àwọn kan sí wà níbẹ̀ tí wọ́n ń wò pẹ̀lú ìfura bóyá yíò wo okùnrin náà sàn ní ọjọ́ ìsimi kí wọn kí ó le ka ẹ̀sùn sií lọrùn. 3 Jésù sọ fún ọkùnrin tí apá rẹ rọ naa, "Dìde kí o sì dúró ni àárín àwọn ènìyàn yí." 4 Lẹ́hìn náà, ó bi àwọn ènìyàn naa léèré pé: Ǹjẹ́ ó bà òfin mu láti ṣerere ní ọjọ́ ìsimi tàbí ṣe búburú; lati gba ẹ̀mí là tàbí láti pa? Sùgbọ́n wọ́n dákẹ lai sọ̀rọ̀. 5 Ó sí wò yí ká pẹ̀lú ìbínú, àti pé inú rẹ bàjẹ́ nítorí àyà líle wọn, ó sì wí fun okùnrin náà pé, "Na ọwọ́ rẹ jade." Ó sì na ọwọ́ rẹ jáde, ó sí bọ̀ sípò. 6 Àwọn Farisí sì jáde lojukan nàà wọn si bẹ̀rẹ̀ si gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn Olùtẹ̀lé Hẹ́ródù bí wọn ó se pa Jésù. 7 Lẹ́yìn naa Jésù pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ sì lọ sí odò Gálílì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn sí tèlé wọn lati Gálílì ati lati Judia. 8 Láti Jerusalemu ati lati ilẹ̀ àwọn ará Édómù ati lati ẹ̀yìn odò Jódánì wa àti àgbègbè àwọn ará Tireni oun Sidoni wa. Ńigbá tí wọ́n sí gbọ́ àwọn ohun àrà tí à ń ti ọ́wọ rẹ̀ se ọ̀pọ́ àwọn ènìyàn tọọ wa. 9 Ó sì rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ pe kí wọn kí ó seètò ọkọ̀ ojú omi kékeré kan sílẹ̀ fun ohun nítor´ ọ̀pọ̀ ènìyàn, kí wọn kí ó ma bá tẹẹ́ pa. 10 Ńitorí tí o tí wo ọ̀pọ̀ ènìyàn sàn ẹnikọ̀ọ̀kan tí ó ní ìpónjú ń gbìyàjú lati fi ọwọ́ kan an bí o tì wù kí o rí. 11 Ńigbà kuú gbà tí àwọn ẹ̀mì aìmọ́ bá ri, wọn a tẹríba níwájú rẹ pẹ̀lú ariwo, wọn a wípé, "Ìwọ ni Ọmọ Olórun." 12 Ó sì pa wọn lẹ́nu mọ́ pé kí wọn máá se fi òun hàn. 13 Ó sì gùn orí òkè lọ, ó sì pe àwọn tí ò wuú, wọ́n sí tọọ́ wá. 14 Ó yan àwon méjìlá (tí òhun tìkara rẹ̀ pè ní aposteli), kí wọn kí ó le wà pẹ́lu rẹ̀ ati kí òhun le rán wọn lọ lati polongo ìhìn naa 15 ati lati ni àse lati lé àwọn èmí èsù jáde. 16 Lẹ́yìn èyí ó yan àwọn méjìlá: Símónì, ẹni tí ó pè ní Pétérù; 17 Jákọ́bù ọmọ Zébédè ati Jòhánù arákùnrin Jákọ́bù, àwọn ẹni tí ó pè ní Bòánájì, èyí tí ó túmọ̀ sí, àwọn ọmọ àrá; 18 ati Áńdérù, Fílípì, Batolómíù, Mátíù, Tọ́másì, Jákọ́bù ọmọ Áfáúsì, Tádáúsì, Símónì alàjàgbara 19 ati Júdásì Ìskáriọ́tù, ẹni tí yoò fií hàn. 20 Lẹ́yí èyí o lọ́ sí ilé, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kójọ lẹẹ̀kan si tó bẹ̀ tí wọn kòle ràyè fún oúnjẹ. 21 Nígbà tí àwọn ẹbí rẹ sì gbọ́ nípa ohun tió ń sẹlẹ̀, wọ́n jáde lati lọ mú nitórití wọ́n wípé "kò mọ ohún tió ń se." 22 Àwọn Akọ̀wé tí ó ti Jerusalemu wá wípé, "ẹ̀mí beélsébúbù ti gbé e wọ̀" àti wípé "nípa olórí àwọn ẹ̀mí òkùnkùn ni ó ń lé áwọn ẹ̀mí òkùnkùn jáde." 23 Jésù sì pe àwon ọmọ ẹ̀yìn rẹ sí apá kan ó sì pa òwe kan fún wọn wípé, "bá wo ni sátánì se le maà lé sátánì jáde?" 24 tí ìjọba kan bá yapa sí ara rẹ̀, ìjoba naa kò le serere 25 tí ilé kan bá yapa sí ara rẹ̀ ilé naa kole dúró. 26 Bí sàtánì bá dìde tako ara rẹ̀, a yapa àti pé òhun kí o lè dúró sùgbọ́n òpín dé ba. 27 sùgbọ́n kò sí ẹni tí o lé wọ ilé alágbára okùnrin lọ kí ó sì kó lí ẹrù lọ láì kọ́kọ́ de okùnrin alágbára naa, lẹ́yìn na a sì ko lí ẹrù lọ. 28 Lootọ ni mo wí fun yín, gbogbo ẹ̀sẹ̀ àwọn ọmọ ènìyàn li ó ní ìdáríjì ati àwọn ọ̀rọ̀ òdì tí wọ́n sọ jáde, 29 sùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí o bá sọ̀rọ̀ òdì tako ẹ̀mí mímọ́ ki yíò ri ìdáríjì gba lailai sùgbọ́n ó jẹ̀bi ẹ̀sẹ̀ ayérayé 30 Jésù sọ ǹkan yí nítorípé wọ́n sọ pé "Ó ní ẹ̀mí aìmọ́" 31 Léyìn èyí ìyá rẹ ati àwọn arákùnrin rẹ wa, wọ́n dúró lóde. Wón sì rańsẹ́ si pe ki o wa lẹ́sẹ̀kesè. 32 Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn si jókòó yi ka, wọ́n sì sọ fun wípé, "Ìyá rẹ ati àwọn arákùnrin rẹ dúró li òde, wọ́n wá ọ́ kiri " 33 Ó sì dá wọn lóhùn wípé, "ta ni ìyáà mi ati àwon arákùnkun mi?" 34 ó sì wo àwon ènìyàn tí ó jòkoó yíi ká, ó sì wípé, "Wo ìyáà mi ati àwon arákùnrin mi" 35 ẹnikẹ́ni tí ó bá se ìfé Ọlọ́run òhun ni arákùnrin mi, arábìnrin mi ati ìyá mi.

Chapter 5

1 Wọ̀n wá sí apa´keji`òkun, sí agbègbè àwọn Kérásènè. 2 Nígbàtí Jésù sí jáde kúrò nínú ọkọ̀ ojú omi, lẹ́ṣẹ̀kẹṣẹ̀ ọkuǹrin kan sí tọ̀ wá láti inù isà-okú tí óní èmi'-àimọ. 3 Ọkùnrin náà ma ńgbé nínú isà-òkú . Kò sì si ẹni tí o le dìímú, koda pelu ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀. 4 Wón ti ma ń dé è lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà pẹ̀lú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ ní ọwọ́ àtì ẹsẹ̀. Ọkùnrin yìí má ń gé ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ tọwọ̀ atì tẹsẹ̀ sí wẹ́wẹ́. kòsí sí ẹni tí agbára rẹ̀ káa. 5 Ní gbogbo ọ̀sán àti òru ni isà-òkú àti ní àwọn orí-òkè, Ó ma ń pariwo jáde Ó si ma tún ya ara rẹ̀ lára pẹ̀lú àwon òkúta tí ó mú. 6 Nígbàtí ó rí Jésù láti jìnnàjìnnà, ó sáré si, o sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 7 Ó pariwo jade lohùn rara, "Ki ni mo ni se pẹ̀lú rẹ, Jésù Ọmọ Ọlọ́run ọ̀gá ògo? Mo bẹ Ọ lórúkọ̀ Ọlọrun nìkan, máse fòró mi." 8 Nítorí ti O ti ń sọ fún "jáde kúrò lára ọkúnrin náà, ìwọ ẹ̀mi àìmọ́." 9 Ó sì bi lere, "Kínni orúko re?" Ó da lóhùn wípé, "Orúko mi ni Lígíónì, nítorí wípé a pọ̀." 10 O bẹ̀, o sì tún bẹ ẹ, láti ma lé àwọn kúrò ní agbègbè náà. 11 Ó sì se, agbo àwọn ẹlẹ́dẹ̀ sì jẹun lórí òkè, 12 Wọ́n sì bẹ́ẹ̀, wípé, "Rán wa lọ sí inú agbo ẹlẹ́dẹ̀; kí a sì wọ inú wọn lọ." 13 Ó sì gbà wọ́n láyè; àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà sì jáde, wọ́n sì wọnù àwọn agbo ẹlẹ́dẹ̀ lọ, wọ́n sì sáré sọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkun, bí ẹgbẹ̀rún méjì ẹlẹ́dẹ̀ si parun sínú òkun. 14 Àwọn tí ó fi oúnjẹ fún àwọn elẹ́dẹ̀ náà sí sálọ, wọ́n sí ròyìn ohun tí ó sẹlẹ̀ lárin ìlú àti ní gbogbo agbègbè, àwọn ènìyàn sì jáde láti rí ohun tí ó sẹlẹ̀. 15 Àwon ènìyàn sì wá sọ́dọ̀ Jésù, wọ́n sì rí ọkùnrin ẹlẹ́mìí àìmọ́ náà, èyí tí ó kún fún Lígíónì, ó jóko pẹ̀lú ẹ̀wù lọ́rùn àti ọpọlọ tó yè koro. 16 Àwọn tí ó sì rí ohun tí ó sẹlẹ̀ sí ọkùnrin ẹlẹ́mì àìmọ́ náà ròyìn ohun tí ó sẹlẹ̀ ní kíkún fún wọn, wọ́n sì ròyìn fún wọn nípa ohun tí ó sẹlẹ̀ sí àwon ẹlẹ́dẹ̀. 17 Nígbànà ní wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sì ní bẹ̀ pé kó fi agbègbè àwọn sílẹ̀. 18 Nígbàtí ó wọnú ọkọ̀ ojú omi lọ, ọkùnrin aláimọ́ náà bẹ̀ pé kí ohun le wà pẹ́lù rẹ. 19 Sùgbọ́n Jésù kò gbàá láyè, sùgbọ́n ó dá lóhùn wípé, "Lọ sí ilé rẹ àti ọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí re, kí ó royin ohun tí Olúwa tí se fún ọ àti bí ó ti fi anu han si ọ. 20 Ó sì lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí polongo àwọn ohun ń la tí Jésù tí se fún ni agbègbé Dẹ́kápólísì, ẹnu sí yà gbogbo ènìyàn. 21 Nígbàtí Jésù tí re kojá sí òdì kejì, nínú ọkọ̀ ojú omi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn yii ká, bí ó ti wà lẹgbẹ òkun. 22 Ọ̀kan nínú àwon olùdarí sínágọ́gú, ẹní tí orúkọ rẹ̀ ńjẹ́ Jáírù, ó wáà, nígbàtí ó sì ri, o wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 23 Ó bẹ̀ ẹ́, ó sì tún bẹ̀ wípé, ọmọ mi obìnrin kékeré fẹ́rẹ̀ kú. Mo bẹ̀ Ọ́, wá dá ọwọ́ rẹ lee kí ó le padà bọ̀ sí pò kí o sì wà ní àláfíà. 24 Nítorína Ó bá lo. ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì ba lọ àti pé wọ́n súmọ́ Ó pẹ́kípẹ́kí ní agbègbè náà. 25 Obìnrin kan sí wá ní bẹ tí o ní isun ẹ̀jẹ̀ fún ọdún méjìlá. 26 Ó tí ní orísiríìsi ìlàkọjá pẹ̀lú àwon onísègùn àti pé ó ti ná ohun gbogbo tí óní, sùgbọ́n, kàkà kí o sàn se ló ń le koko si. 27 Nígbàtí o sì gbó ìròyìn nípa Jésù, ò sí tọ̀ wá larin àwon èrò, ò dúró lẹ́yìn rẹ̀, ó sì fi ọwọ́ kan etí asọ Rẹ̀. 28 Nítorí tí ó wípé, "tí mo bá le fọwọ́ kan etí asọ Rẹ̀, èmi yóò gba ìwòsàn. 29 "Nígbàtí o fọwọ́ kan, ìsun ẹ̀jẹ̀ náà dáwọ́ dúró, ó sì mọ̀ lára rẹ̀ wípé ìsun ẹ̀jẹ̀ náà tí dáwọ́ dúró, pé ohun ti rí ìwòsàn nínú gbogbo ìdàmù náà. 30 Jésù sì ní ìmọ̀lára lẹ́ṣẹ̀kẹṣẹ̀ wípé agbára ti jáde kúrò lára òhun. Ó wò yíká láàrín èrò wípé, "tani ó fọwọ́ kan asọ mi?". 31 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ wí fún pé, "O ri bi àwọn ènìyàn yìí tí yípo Rẹ, ó sì ni, "tani ó fọwọ́ kàn mí?" 32 Jésù wò yíká láti rí ẹni tó ṣe eléyìí. 33 Obìnrin náà, nítorí ó mọ ohun tí ó sẹlẹ̀, ó si bẹ̀rù pẹ̀lú ìwárìrì. Ó wa, ó sì kùnlẹ́ níwáju Rẹ̀, ò sí sọ òtítọ́ fún ún. 34 Ò sí wí fun pè, "Obìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá. Ma lọ lalafia ki o si gba ìwòsàn kúrò nínú àrùn rẹ. 35 Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọn kan wá láti ọ̀dọ̀ olórí sínágọ́gú, wípé "Ọmọ rẹ obìnrin ti kú, kí ló dé tí ó ńyọ Olùkóni lẹ́nu?" 36 Nígbàtí ohun tí wọ́n sọ dé etí ìgbo Jésù, Ó sọ fún olórí sínágọ́gú pé "Má bẹ̀rú, ìwọ sá gbàgbó". 37 Kò si gba ẹnikẹ́ni laye láti tẹ̀le, àyàfi Pétérù, Jákọ́bù ati Jòhánù arákùnrin Jákọ́bù. 38 Wọ́n sì wá sí ilé olórí sínágọ́gú, Ó sì ri àwọn ènìyàn tí wọ́n pariwo; wọ́n sọkún, wọ́n sì ké rora sókè. 39 Nígbàtí Ò sí wọ ilé náà, Ó wí fún wọ́n wípé, "Kí lódé tí ẹ ń banújẹ́ tí ẹ ṣì ńsọkún? Ọmọ náà kò kú, sùgbọ́n ó sùn." 40 Wọ́n sì fi rẹ́rin. Sùgbọ́n Ó ti gbogbo wọ́n si ta. Ó sì mu baba ọmọ náà, ìyá ọmọ náà àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, Ó sì wọ́lè sí ibi tí ọmọ náà wa. 41 Ó sì mu ọwọ́ ọmọ náà Ó sì wí fún wípé, "Talitha Koum!" èyí tí ó túmọ̀ sí wípé, "ọmọbìnrin, mo wí fún ọ, dìdé." 42 Lójú kanáà, ọmọ náà didé, ó sì ń rìn (Ó jé ọmọ ọdún méjìlá nigbana). Lẹ́sẹ̀kánnà ẹnu yà wọ́n, ìbẹ̀rù bojo sì mú ọkàn wọn. 43 Ó sì pàsẹ fún wọn wípé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ mọ̀ ní pa rẹ̀. Ó sì wí fún wọn wípé, kí wọn fun lóúnjẹ jẹ.

Chapter 7

1 Àwọn Farisí àti àwọn akọ̀wé tí wọ́n wá láti Jèrúsálẹ́mù pagbo yí Jésù ká. 2 Wọ́n ríi wípé àwọn kan nínú àwọn ọmọẹ̀yìn Rẹ̀ ń jẹhun pẹ̀lú ọwọ́ àìmọ́, eyí ni, láì fọwọ́ . 3 (Nítorípé àwọn Farisí àti gbogbo àwọn Júù kìí jẹhun láì jẹ́ pé wọ́n bá fọwọ́, nítorípé wọ́n fi ọwọ́ gidi mú àsá àwọn àgbààgbà. 4 Tí àwọn Farisí bá ti ọjà dé, wọn kìí jẹhun bíkòsepé wọ́n bá kọ́kọ́ wẹ ara wọn, bẹ́ẹ̀ni wọ́n sì di àwọn àsà míràn náà mú sinsin, bíi fífọ ife ìmumi, ìkòkò, ohun èlò idẹ, àti àwọn tábìlì tí wọ́n bá fi jẹhun.) 5 Àwọn Farisí àti àwọn Akọ̀wé bèèrè lọ́wọ́ ọ Jésù, wípé, "Kílódé tí àwọn ọmọẹ̀yìn Rẹ kìí rìn ní ìbámu pẹ̀lú àsà àwọn àgbààgbà, nítorí wọ́n jẹ oúnjẹ wọn láì fọwọ́." 6 Ṣùgbọ́n Ó wí fún wọn pé, "Ìsáyà sọtẹ́lẹ̀ dáradára nípa ẹ̀yin àgàbàgebè. Ó kọọ́ pé, àwọn ènìyàn yíì ń fi ètè wọn bu ọlá fún mi, sùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí ọ̀dọ̀ mi. 7 Ìjọ́sìn tí kò wúlò ni wọ́n ń fún mi, wọ́n ń kọ̀ni ní ìlànà ènìyàn bíi àgbékalẹ̀ ara wọn.' 8 Ẹ pa òfin Ọlọ́run tì, ẹ sì di àsà ènìyàn mún sinsin." 9 Ó sì tún wí fún wọn pé, "Ẹ rò pé ẹ ti se ohun tí ó dára tó lójú ara yín, tí ẹ kọ òfin Ọlọ́run kí ẹ le se àmúlò àsà àtọwọ́dọ́wọ́ tiyín!" 10 Sebí Mósè wípé, 'Bọ̀wọ̀ fún bàbá àti ìyá rẹ,' àti wípé, 'ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ bàbá tàbí ìyá rẹ̀ làì dára kíkú ni yíó kùú.' 13 11 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wípé, 'Bí ènìyàn kan bá sọ fún bàbá tàbí ìya rẹ̀ pé, "Ìrànlọ́wọ́ yòówù tí ó yẹ tí o kò bá rí gbà lọ́wọ́ọ̀ mi Kóbánì ni,"' (èyí ni, "Mo ti fi fún Ọlọ́run")- 12 Ẹ kò wá jẹ́ kí ọmọ le se ǹkankan fún bàbá tàbí ìya rẹ̀ mọ́. v 13 Ẹ ń pa òfin Ọlọ́run rẹ́ nípa àsà àtọwọ́dọ́wọ́ tí ẹ gbé kalẹ̀. àti ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan bíi irú ìwọ̀nyí ni ẹ se. 14 Ó tún pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, Ó sì wí fún wọn pé, "Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ẹ tẹ́tí gbọ́ mi, kí òye kí ó sì yé yín. 15 Kòsí ohunkóhun láti òde àgọ́ ara ènìyàn tí ó le sọ ènìyàn di aláìmó nígbàtí ó báwọ inú ènìyàn. Bíkòse ohun tí ó jáde wá láti inú ènìyàn sí ìta ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìse, ni ó ń sọ ènìyàn di aláìmọ́." 16 "Bí ẹnikẹ́ni bá ní etí láti fi gbọ́, jẹ́ kí ó gbó." 17 Ní àkókò yìí, nígbàtí Jésù kúrò lọ́dọ́ àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn náà tí Ó sì wọ inú ilé, àwọn ọmọẹ̀yìn Rẹ̀ bií léèrè ìbéèrè lórí òwe náà. 18 Jésù dá wọn lóhùn wípé, "Ẹ̀yin kò tún tíì lóye èyí náà ni bíí? Sé ẹ kò tíì ri pé kòsí ohunkóhun láti òde àgọ́ ara ènìyàn tí ó le sọ ènìyàn di aláìmọ́ nígbàtí ó báwọ inú ènìyàn, 19 nítorípé kò le wọ inú ọkàn lọ, ṣùgbọ́n ó ń lọ sí inú ikùn ènìyàn tí yíó sì gba ibẹ̀ di ohun tí a ya ìgbẹ́ rẹ̀ sí ilé ìyàgbẹ́?" Jésù sọ gbogbo ohúnjẹ di mímọ́ pẹ̀lú gbólóhùn ọ̀rọ̀ yìí. 20 Ó wípé, ọ̀rọ̀ àti ìse tí ó jáde wá láti inú ènìyàn sí òde ni ó ń sọ ènìyàn di aláaìmọ́. 21 Nítorípé nínú ènìyàn, láti inú ọkàn wá ni àwọn èrò burúkú ti ń jáde wá, ìsekúse, olè jíjà, ìpànìyàn, 22 panságà, ojúkòkúrò, ìkà, ẹlẹ̀tàn, ọlọgbọ́n lójú ara rẹ̀, ìlàra, abaníjẹ́, agbéraga, aláìnírònú. 23 Láti inú ọkàn ni gbogbo ibi wọ̀nyí ti máa ń jáde wá, àwọn ló sì ń so ènìyàn di aláìmọ́." 24 Ó sì dìde kúrò níbẹ̀, Ó sì lọ sí agbègbè Tírè àti Sídónì. Ó wọ inú ilé kan, kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀ pé Òun wà níbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò le sápamọ́n fún wọn. 25 Ṣùgbọ́n lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, obìnrin kan tí ọmọ rè ní ẹ̀mí àìmọ́, gbọ́ nípa rẹ̀, ó wá, ó sì kúnlẹ̀ sílẹ̀ ní ibi ẹsẹ̀ rẹ̀. 26 Ara Gíríkì ni obìnrin náà ń se, ọmọ bíbí Sirofẹ́níkà níí se. Ó bẹ Jésù kí ó bá òun lé ẹ̀mí èsù inú ọmọbìnrin òun jáde. 27 Jésù wí fún un pé, "Jẹ́ kí àwọn ọmọ ilé Ísrẹ́lì kọ́kọ́ jẹhun ná, nítorípé kò dára kí á wá lọ gbé ohunjẹ àwọn ọmọ kí á lọ gbée fún àwọn kéfèrí." 28 Ṣùgbọ́n Obìnrin yìí dáhùn, ó wí fún Jésù pé, "Bẹ́ẹ̀ni, Olúwa, àwọn kèfèrí pàápàá le jẹ ẹ̀rúnrún ohúnjẹ àwọn ọmọ Ísrẹ́lì tí ó bá bọ́ sí ilẹ̀ láti oríi tábìlì." 29 Ó wí fún un pé, "Nítorítí ìwọ́ sọ èyí, máa lọ lómìnira. Ẹ̀mí èsù náà ti jáde kúrò làra ọmọbìnrin rẹ." 30 Obìnrin náà sì padà lọ sí ilé rẹ̀, ó sì bá ọmọbìnrin rẹ̀ tí ó ń sùn lóríi bẹ́ẹ̀dì, àti wípé ẹ̀mí èsù náà ti fíi sílẹ̀ lọ. 31 Jésù tún kúrò ní agbègbè Tírè, Ó sì gba inú Sídónì lọ sí òkun Gálílì, ní ìgòkè lọ sí agbègbè Dẹ́kápólísì. 32 Àwọn ènìyàn gbé ẹnìkan tí kò gbọ́ ọ̀rọ̀, tí ó sì nira fún láti sọ̀rọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n sì bẹ̀bẹ̀ wípé kí Jésù wòó sàn. 35 34 Jésù mú ọkùnrin náà jáde sí ẹ̀gbẹ́ kan kúrò láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyan, Ó sì ń fi ìka rẹ̀ bọ ọkùnrin nàà létí, lẹ́yìn ìgbàtí Ó tutọ́ sí ọwọ́ Rẹ̀, Ó fi ọwọ́ kan ọkùnrin náà ní ahọ́n. 33 Jésù gbé ojú wo òkè ọ̀run, Ó mí kanlẹ̀, Ó wí fún ọkùnrin náà pé, "Éfátà" èyí tíí se "Ṣí!" Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ etí ìgbọ́ràn rè sì ṣí, Jésù sì tú ahọ́n rẹ̀ sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àìlé sọ̀rọ̀, ó sì sọ̀rọ̀ yékéyéké. 36 Jésù kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n máse sọ fún ẹni kankan. Sùgbọ́n bí Ó ti ń kìlọ̀ fún wọn tó bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n sì ń polongo Rẹ̀ síi. 37 Ẹnu ya àwọn ènìyàn kọjá gidigidi, wọ́n sì ń wípé, "Ó ti se gbogbo ǹkan dáradára. Ó mú kí adití gbọ́ràn, Ó sì mú kí ẹnití kò le sọ̀rọ̀ di ẹnití ó ńsọ̀rọ̀."

Chapter 9

1 Jésù sì wi fún wọn pé, "Lóòtọ́ọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú yín tí ó dúró níhìńyí ní kì yíò rí ikú kí wọ́n tó rí ìjọba ọlọ́run tí yíò dè pẹ̀lú agbára." 2 Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà, Jésù mú Pétérù àti Jákọ́bù àtiJòhánù pẹ̀lú Rẹ̀ lọ sórí òkè gíga, wọ́n dáwà níbẹ̀. A sì paá láradà níwájú wọn. 3 Aṣọ Rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí tàn bí i mọ̀nàmọ́ná, ó funfun bí ọṣẹ ìfọṣọ ayé kan ìbá fi fọ̀ ọ́ lọ. 4 Lẹ́hìn náà, Èlíjà àti Mósè fara hàn wọ́n, wọ́n sì ń bá Jésù sọ̀rọ̀. Pétérù dáhùn ó sì wí fún Jésù pé, 5 "Olùkọ́ni, ó dára fún wa láti máa gbé ibíyìí, nítorínà, Ẹ jẹ́ ká kọ́ ilé'gbe mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mósè, àti ọ̀kan fún Èlíjà." 6 (Nítorí Pétérù kò mọ ohun tí yíò sọ, nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi) 7 Àwọ̀ sánmọ́ sì ṣíjibòwọ́n mọ́lẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹṣè, ohùn kan jáde wá láti inú àwọ̀ọsánmọ̀ wá wípé, "Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹ máa gbọ́ tirẹ̀." 8 Bí wọ́n ti wò àyíká wọn, wọn kò rí ẹnìkankan pẹ̀lú wọn mọ́, bíkòṣe Jésù nìkan. 9 Bí wọ́n ti ń ti orí òkè sọ̀kalẹ̀, Jésù pàṣẹ fún wọn láti máṣe sọ ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni, títí tí àwọn ọmọ ènìyán yíò fi jí dìde láàrin àwọn òku. 10 Nítorínà, wọ́n pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ láàrin ara wọn, ṣùgbọ́n wọ́n ń jíròrò láàrin ara wọn nípa ohun tí "jíjí dìde kúrò láàrin àwọn òku" túmọ̀ sí. 11 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn bi Jésù léèrè pé, "Èéṣe tí àwọn akọ̀wé fi ṣọ wípé Èlíjà ni ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wá."? 12 Jésù wí fún wọn pé, "Èlíjà ti kọ́kọ́ wá ná láti mún ohungbogbo padàbòsípò.Èéṣe tí a wá fi kọ̀wé rẹ̀ pé Ọmọ ènìyàn gbọ́dọ́ jìyà ohun púpọ̀ kí á sì se Ṣé bíi ẹni tí kòní láárii? 13 Ṣùgbọ́n èmi wí fún n yín pé Èlíjá ti wá ná, wọ́n sì seé ohun gbogbo tí ó wù wọ́n síi, gẹ́gẹ́ bí ìwé mímọ́ ti wí nípa rẹ̀." 14 Nígbàtí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yókù, wọ́n sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò yí wọn ká bẹ́ẹ̀ni àwọn akọ̀wé sì ń bá wọn wíjọ́. 15 Bí wọ́n ti rí Jésù, ẹnu ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò náà bẹ́ẹ̀ni wọ́n sáré pàdé rẹ̀ wọ́n sì kíi. 16 Ó bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀ wípé, "Kíni ẹ̀yin bá wọn se àríyànjiyàn síi?" 17 Ẹnìkan láàrín èrò sì dáhùn ó wípé, "Olùkó, mo mú ọmọ mi tọ̀ Ọ́ wá.Ẹ̀míkẹ́mìí kan ti jẹ́ kó ya odi 18 Ó má ń gbáa mú, á sì gbée sánlẹ̀, bẹ́ẹ̀ni ó má ń mú kí ó máa pòfóló, kí ó sì ma payín keke, òun á sì gan pa. Mo bẹ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ kí wọ́n leèle jáde kúrò nínú rẹ̀ sùgbọ́n wọn kò leè ṣeé." 19 Ó sì wí fun wọn pé, "Ìran aláìgbàgbọ́, èmi ó ti bá n yín gbé pẹ́ tó? Èmi ó ti mú sùúrù pẹ́ tó fún n yín? Mú u wá fún mi.?" 20 Wọ́n mú ọmọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbàtí ẹ̀mí náà rí Jésù, ó jẹ́ kí gììrì ki ọmọ náà lójijì. Ọmọkùnrin náà ṣubú lulẹ̀ ó sì ń pòfóló. 21 Jésù bá bi bàbá ọmọ náà, "Ó ti pẹ́ tó tí ti wà nírú ipò yìí?" Bàbá rẹ̀ dáhùn ówípé, "Láti ìgbà èwe rẹ̀ ni. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, 22 ó tilẹ̀ má n gbe jù sínú iná tàbí sínú omi láti paá lára nígbà míràn. Bí O bá le se ohun kóhun, sàánú fún wa kí o sì ràn wá lọ́wọ́." 23 Jésù wí fún pé, "Bí ìwọ bá nípá? Ohun gbogbo ni ṣíṣe fún àwọn tí ó gbàgbọ́." 24 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bàbá ọmọ náà kígbe sókè wípé, "Mo gbàgbọ́! Ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ´." 25 Nígbàtí Jésù rí ọ̀pọ̀ èrò tó n wá sọ́dọ̀ rẹ̀, Ó bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó wípé, "Ìwọ ẹ̀mí odi àti ìdití, mo pàṣẹ fún ọ, jáde kúrò lára rẹ̀ kí o má sì ṣe padà síbẹ̀ mọ́." 26 kígbe tòò ó sì jẹ́ kí gììrì ki ọmọ náà gidigidi, ó sì jáde kúrò lára rẹ̀. Ọmọkùnrin náà sì ń wò bíi ẹnití ó ti kú, tóbẹ̀ẹ̀ tí àwọn ènìyàn fi wí pé, "ó ti kú". 27 Sùgbọ́n Jésù gbá ọwọ́ ọmọ náà mú, Ó fàá sókè, ọmọ náà sì dìde dúró. 28 Nígbàtí Jésù sì wọlé wá, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ bií ní ìkọ̀kọ̀ pé, "Èéṣe tí àwa kò fi le è lèe jáde." 29 Ó dáhùn ósì wí fún won pé, "Irú èyí kò le ṣééṣe bíkòṣe nípasẹ̀ àdúrá." 30 Wọ́n sì jáde lọ kúrò níbẹ̀, wọ́n gba agbègbè Gálílì lọ. Jésù kò fẹ́ kí ẹnìkankan kí ó mọ ibi tí àwọn wà, 31 nítorí tí Ó n kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Rẹ̀. Ó sọ fún wọn wípé, "A ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́, wọn ó sì ṣe ikú pa Á. Lẹ́yìn ìgbà tí Ó bá kú tán, lẹ́yìn ọjọ́ kẹta yíò jí dìde , 32 Sùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ó n sọ yìí kò yé wọn, ẹ̀rù si n bà wọ́n láti bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀. 33 Lẹ́yìn náà ni wọ́n wá sí Kápánámù. Nígbàtí ó sì ti wọ sínú ilé kan, Ó biwọ́n léèrè pé, "Kíni ẹ̀yin n bá ara yín sọ lójú ọ̀nà.?" 34 Wọ́n sì dákẹ́ jẹ́ẹ́. Nítorítí wọ́n ti n ṣe àríyànjiyàn láàrin ara wọn níti ẹnití ó pọ̀jùlọ láàrin wọn. 35 Nígbàtí Ó jókòó, Ó pe àwọn méjìlá sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀ ó sì wí fún wọn pé, "bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ se ẹni àkọ́kọ́, Oun ni yíò jẹ́ ẹni ìkẹyìn àti ìránsẹ́ gbogbo ènìyàn." 36 Ó mú ọmọ kékeré kan Ó sì fi sí ààrin wọn. Jésù gbé e lọ́wọ́ Rẹ̀ ó sì wí fún wọn pé, 37 "Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọmọdé kékeré yìí ní orúko mi, ó gbà mí pẹ̀lú, bí ẹnikẹ́ni básì gbà mí, kò gba Èmi nìkan, sùgbọ́n ó gba Ẹni tí ó rán mi pẹ̀lú." 38 Johánù wí fún Un pé, "Àwá rí ẹnìkan tí ó n le àwọn ẹ̀mi àìmọ́ jáde ní orúkọ Rẹ̀, àwa si dáalẹ́kun, nítorí kò tọ̀wálẹ́yìn." 39 Ṣùgbọ́n Jésù wí fún pé, "ẹ máṣe dá wọn lẹ́kun nítorípé kò sí ẹnikẹ́ni tí yíò ṣe iṣẹ́ agbára ní orúkọ mi tí o jẹ́ sọ ohun búburú nípa mi." 40 Ẹnikẹ́ni tí kòba sè ìlòdì síwa, ó wà pẹ̀lú wa. 41 Ẹnikẹ́ni tí ó fi ife omi kékeré fún ni nítorí tí ó jẹ́ ti Kristi, lóòtítọ́ ni mo sọ fún yín, kì yó pàdánù èrè rẹ̀. 44 42 Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré tí o gbàgbọ́ nínú mi kọsẹ̀, ó sàn fun kí á so ọọlọ nlá mọ́-ọn lọ́rùn kí á sì sọọ́ sìnú òkun. 43 Bí ọwọ́ rẹ kan bá mú ọ kọsẹ̀, gée dànù. Ó sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run bíi akéwọ́ jù kí o lọ sí ọ̀run àpáàdì pẹ̀lú ọwọ́ méjèèjì lọ, nínú iná àjóòkú. 45 Bí ẹsẹ̀ rẹ kan bá mú ọ kọsẹ̀ pẹ̀lú, gée sọnù. Nitorí ó sàn fún ọ láti wọ Ìjọba ọ̀run bíi akésẹ̀ jù fún ọ pẹ̀lú ẹsẹ̀ méjèèjì, kí á sì gbé ọ jù sínú iná ọ̀run àpáàdì lọ 46 47 Bí ojú rẹ kan bá mú ọ kọsẹ̀, yọọ́ dànù. Nítorí ó sàn fún ọ láti wọ Ìjọba ọ̀run pẹ̀lú ojú kan jù kí o ní ojú méjèèjì kí á sì gbe ọ sọ sínú iná ọ̀run àpáàdì, 48 níbití ìpáàrà wọn kììkú, bẹ́ẹ̀ni iná wọn kììkú. 49 Nítorí olúkúlùkù ni a o fi iyọ̀ mú dùn pẹ̀lú iná. 50 Iyọ̀ dára, ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá sọ adùn rẹ̀ nù, báwo ni a o ṣe mú dùn padà? Ẹní iyọ̀ láàrin ara yín, ki ẹ sì wà ní àlàáfsíà pẹ̀lú ara yín."

Chapter 10

1 Jésù fi ibẹ̀ sílẹ̀ ó lọ sí agbègbè Jùdéà àti sí ìkọjá odò Jọ́rdánì, ọ̀pọ̀ àwọn èrò sì tún tọ̀ọ́ wá. ó tún nkọ́ wọn lẹ́ẹ̀kan si gẹ́gẹ́bí ó ti má n se. 2 Nígbànáà ni àwọn Farisí wá sọ́dọ̀ọ rẹ̀ láti dán-an wò wọ́n bèrè wípé, " ǹjẹ́ ó bá òfin mu kí ọkọ kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀?" 3 ó dá wọn lóhùn, " kínni Mósè palásẹ fún yín?" 4 Wọ́n wípé, "Mósè fi àyè gba ọkùnrin láti kọ ìwé ìkọ̀sílẹ̀ kí ó sì lée jáde." 5 "Nítorí ọkàn líle yín ni ó se kọ òfin wọ̀nyí fún yín," Jésù wí fún wọn bẹ́ẹ̀. 6 Ṣùgbọ́n láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìṣẹ̀dá, 'Ọlọ́run dá wọn ní akọ àti abo'. 7 'Fún ìdí èyí ni ọkùnrin yó se fi bàbá àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ tí yò si faramọ́ aya rẹ̀, 8 àwọn méjèejì yó sì di ara kàn.' wọ́n kìí sì se méjì mọ́, bí kò se ara kàn. 9 Nítorínàa, ohun tí Ọlọ́run bá ti so pọ̀ di ọ̀kan, kí ẹnikẹ́ni má se pín wọn lọ́tọ̀ọtọ̀." 10 Nígbàtí wọ́n wà nínú ilé, àwọn ọmọ ẹyìn bèrè lẹ́ẹ̀kan si nípa èyí. 11 Ó wí fún wọn pé, "ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ tí ó si gbé obìnrin míràn ní ìyàwó ó se panságà síi. 12 Bí obìnrin bá kọ ọkọ rẹ sílẹ̀ tí ó si fẹ́ ọkùnrin míràn, ó se panságà." 13 Lẹ́yìn náà wọ́n kó àwọn ọmọ wọn wẹẹrẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ kí ó le fi ọwọ́ kàn wọ́n, sùgbọ́n àwọn ọmọ ẹyìn bá wọn wí. 14 Ṣùgbọ́n nígbàtí Jésù se àkíyèsi rẹ̀, inú rẹ̀ kò dùn rárá ó sì wí fún wọn pé "ẹ jẹ́kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi, ẹ máse dí wọn lọ́wọ́, nítorí ìjọba Ọlọ́run wà fún àwọn tó dàbí wọn. 15 Lóòtọ́ ni mo sọ fún yín, ẹnikẹ́ni tí kò bá fẹ gba ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré kan dájúdájú kò ní leè wọlé sí ibẹ̀." 16 Lẹ́yìn náà ó gbé àwọn ọmọ kékeré sí apáa rẹ̀ ó sì bùkún fún wọn bí ó se ńgbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn. 17 Nígbàtí ó bẹ̀rè ìrìnàjò rẹ̀, ọkùnrin kàn sáré tọ̀ọ́ wá ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹẹ̀, ó bèrè " Olùkọ́ni rere, kínni èmi yóò se kín lè jogún iyè ayérayé?" 18 Jésù wípé, kínni ìdí tí o fi pè mí ní rere? Kò sí ẹni rere kan, à fi Ọlọ́run. 19 Ìwọ mọ àwọn òfin: 'máse pànìyàn, máse se panságà, máse jalè, máse jẹ́ẹ̀rí èké, máse rẹ́nijẹ, bu ọlá fún bàbá àti ìyá rẹ'." 20 Okùnrin náà wípé, "Olùkọni, gbogbo ǹkan wọ̀nyí ni mo ti gbọ́ràn sí láti ìgbà tí mo ti wà ní ọ̀dọ́" 21 Jésù wòó ó sì fẹ́ẹ. Ó wí fún pé, " ohùn kan ni o kò ní. O gbọ́dọ̀ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o sì fi fún àwọn aláìní, ìwọ yó sì ní ìsura ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà wá, máa tẹ̀lé mi" 22 Sùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀ yí ojú rẹ̀ korò, ó sì lọ kúrò pèlú ìbànújẹ́ ọkàn, nítorí tí ó ní ọrọ̀ púpọ̀. 23 Jésù sí wo àyíká ó wí fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, "báwo ni yó ti nira tó fún àwọn ọlọ́rọ̀ láti wọ íjọba Ọlọ́run! 24 "Ẹnú ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn sí àwọn ọ̀rọ̀ọ rẹ̀. Sùgbọ́n Jésù tún sọ fún won lẹ́ẹ̀kan si, " Ẹ̀ yin ọmọdé, báwo ni yó se nira tó láti wọ ìjọba Ọlọ́run! 25 Ó rọrùn fun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ kan láti wọ ìjọba Ọlọ́run" 26 Ẹnú sì yà wọ́n gidigidi wọ́n sì ńbá ara wọn sọ̀rọ̀, "taani yóò wá le là bá yì?" 27 Jésù wò wọ́n ó wípé, "pẹ̀lú ènìyàn ó sòro se sùgbọ́n kò rí bẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Nítorí ohun gbogbo ni síse fún Ọlọ́run." 28 Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí báa sọ̀rọ̀, "wòó a ti fi ohun gbogbo sílẹ̀ a sì ti tẹ̀lé ọ." 29 Jésù wípé, lóòtọ́ ni mo wí fún yin, kò sí ẹni tí ó fi ilé, tàbí arákùnrin tàbí arábìnrin tàbí ìyá tàbí bàbá tàbí àwọn ọmọ tàbí ilẹ̀ nítorí tèmi àti nítorí ìyìn-rere 30 tí kì yóò gbàá ní ìlọ́po ọgọ́rùnún ní ayé yìí: ilé àti, arákùnrin, àti arábìnrin, àti ìyá àti àwọn ọmọ àti ilẹ̀ pẹ̀lú inúnibíni àti ní ayé tí ńbọ̀ iyè aìnípẹ̀kun. 31 , Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn ẹni iwájú ní yóò di ẹni ẹ̀yìn àti ẹni ẹ̀yìn yóò sì di ẹni iwájú." 32 Wọ́n wà lójú ọ̀nà wọ́n ńlọ sí Jèrúsálẹ̀mù, Jésù sí ńlọ níwájú wọn. Ẹnú ya àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àti àwọn tí ò ǹtẹ̀le wọn lẹ́yìn ni ẹ̀rù síì ńbà. Lẹ́yìn náà Jésù mú àwọn méjìlá sí ẹ̀gbẹ́ kan ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún wọn ohun tí yóò sẹlẹ̀ sí òun ní kòpẹ́kòpẹ́. 33 "wòó, àwa ńgòkè lọ sí Jèrúsálẹ̀mù, a ó sì fi ọmọ ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé lọ́wọ́. Wọn ó dáa lẹ́bi ikú wọn ó sì fi lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́. 34 Wọn ó fi se ẹlẹ́yà, wọn ó tu itọ́ sí lára, wọn ó nàá pẹ̀lú ẹgba, wọn ó sì paá. Sùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ kẹ̀ta yó dìde 35 Jákọ́bù àti Jòhánnù, àwọn ọmọ Ṣébédè gòkè wá sọ́dọ́ rẹ̀ wọ́n wípé, "Olùkọni, àwa fẹ́ kí ẹ se ohunkóhun tí a bá bèrè fún wa" 36 Ó bi wọ́n pé, kínni ẹ fẹ́ kí èmi ó se fún yín?" 37 " Wọ́n wípé, gbà wá láàyè láti jókòó pẹ̀lú rẹ nínú ògo, ọ̀kan lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ àti èkejì ní ọwọ́ òsì rẹ." 38 Jésù dá wọn lóhùn, ẹ kò mọ ohun tí ẹ̀yin ńbèrè. Ẹ̀ yín a le mu ife tí èmi yóò mu tàbí farada ìtẹ̀bọmi tí a ó fi rì mí bọmi?" 39 Wọ́n wí fún pé, "àwa leè sé" Jésù wí fún wọn pé , ife tí èmi yóò mu ni ẹ̀yin náà yóò mu àti ìtẹ̀bọmi tí èmi ó se ni aó se fún ẹ̀yin náà. 40 Ṣùgbọ́n, ẹni tí yóò jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní ọwọ́ òsì mi, kìí se tèmi láti fúnni bíkòse àwọn tí a ti pèsèe rẹ̀ sílẹ̀ fún." 41 Nígbàtí àwọn ọmọ ẹ̀yìn mẹ́ẹ̀wá yó kù gbọ́ èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bínú sí Jákọ́bù àti Jòhánnù. 42 Jésù pè wọ́n sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ó wípé, "ẹ̀yín mọ̀ pé àwọn tí a kà sí olórí láàrín àwọn kèfèrí má ńlo ipá lórí wọn àti àwọn alásẹ àgbà ńlo ipò àsẹ lórí wọn 43 Ṣùgbọ́n kò gbọdọ̀ rí bẹ́ẹ̀ láàrín yín. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di gíga nínú yín yóò se ọmọ ọ̀dọ̀, 44 àti ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ se asájú nínú yín yóò se ìránsẹ́ gbogbo won. 45 Nítorí ọmọ ènìyàn kò wá pé kí á se ìránsẹ́ fún òun bíkòse láti se ìránsẹ́ fún ẹlòmíràn àti láti yònda ara rẹ̀ fún ìràpàdà ọ̀pọ̀lọpọ̀" 46 Wọ́n wá sí Jẹ́ríkò. Bí ó se fi Jẹ́ríkò sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò, ọmọ Tíméaù, Bátólóméù afọ́jú tí ó ntọrọ, jókòó ní ẹ̀bá ọ̀nà. 47 Nígbàtí ó gbọ́ pé Jésù ti Násárẹ́tì ni, ó bẹ̀rẹ̀ síi kígbe wípé, "Jésù ọmọ Dáfídì sàánú fún mi". 48 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló bá afọ́jú náà wí, pé kí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n ó kígbe lóhùn rara síi "ọmọ Dáfídì sàánú fún mi" 49 Jésù dúró ó sì pàsẹ pé kí wọ́n pèé wá. Wọ́n pe ọkùnrin afọ́jú náà, Ó ńpè ọ́ se bi akin! dìde! Ó ńpè ọ́." 50 Ó ju asọ rẹ̀ sí apákan ó dìde wá sọ́dọ̀ Jésù 51 Jésù dáhùn ó wípé, "Kínni ìwọ́ ńfẹ́ kí èmi kí ó se fún ọ?" Ọkùnrin afọ́jú náà wípé, Rábbì , mo fẹ́ kín rí ran." 52 Nígbànáà ni Jésù wí fun pé, máa lọ ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá" Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó sì rí ran lẹ́ẹ̀kan si, ó sì ńtẹ̀lé wọn lẹ́yìn lójú ọ̀nà.

Chapter 13

1 Bí Jésù ti ń lọ kúrò ni tẹ́ḿpílì, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wí fun pé. "Olùkọ́ni, wo òkúta iyebíye àti àwọn ilé iyebíye!" 2 Ó sì sọ fún n wípé, "Ǹjẹ́ ìwọ́ rí àwọn ilé ńlá yìí? Kò sí ọ̀kan nínú àwọn òkúta wọ̀nyí tí yíò dúró lórí ara wọn tí a kò ní dàwó lulẹ̀. 3 Bí ó ti jòkó ní orí òkè Ólífì ní òdìkejì tẹ́ḿpìlì, Pétérù, Jákọ́bù, Jòhánù, àti Ándérù bi í léérèè níkọ̀kọ̀ pè, 4 Sọ fún wa, nígbàwo ni àwọn ǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀? Kí ni yóò jẹ́ àmìn nígbàtí àwọn ǹkán wọ̀nyí bá fẹ́ ṣẹlẹ̀? 5 Jésù sí bẹ̀rẹ̀ síí sọ́ fun wọn pé, "Ẹ kíyèsára kí ẹnikẹ́ni máṣe ṣì yiń lọ́nà. 6 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóó wàá lórúkọ mì, tí wọ́n yíò sọ pé, 'Èmi ni ẹní nà,' nwọ́n yóò sì ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn lọ́nà. 7 Nígbàtí ẹ̀yin bá ń gbọ́ ìró ogun tàbí àwọn ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun, ẹ máṣe ṣe àníyàn; àwọn ǹkan wọ̀nyí gbọdọ̀ ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kò ì tí dè. 8 Nítorí orílẹ̀èdè yíò dìde sí ara wọn, àti ìjọba lòdì sí ìjọba. Ilẹ̀ ríru yóò wà ní ọpọ̀lọpọ̀ ibi, àti ìyaǹ. Ǹwọ̀nyí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú. 9 Ẹ wà ní ìgbáradì. Nwọn ó jọ̀wọ́ yín fún àwọn ìjòyè, a ó sì nà yín nínú àwọn sínágógù. Ẹ̀yin yóò dúró ní iwájú àwọn gómìnà ati àwọn ọba nítorí mi, bi ẹ̀rí fún wọn. 10 Ṣùgbọ́n a kọ́kọ́ kéde ìhìnrere ní gbogbo orílẹ̀-èdè. 11 Nígbàtí a bá mu yiń tí a sì jọ̀wọ́ yiń lọ́wọ́, ẹ má ṣe ṣàníyàn oun tí ẹ̀yin yíó sọ. Nítorí ní wákàtí náà, a ó fún yiń ní ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin yóò sọ; ki yíò jẹ́ ẹ̀yin ni yóò sọ̀rọ̀, bíkòṣe Ẹ̀mí Mímọ́. 12 Arákùnrin yóò jọ̀wọ́ arákùnrin fún ikú, àti bàbá yóò jọ̀wọ́ ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́. Àwọn ọmọ yio dìde sí àwọn òbi wọn, nwọn yóò sì sọwọ́n di ẹni tí ikú npa. 13 Gbogbo ènìyàn ni yóò kórira yín nítorí orúkọ mi. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá forí tì í dópin, ẹni náà yóò yè. 14 Nígbàtí ẹ bá ń rí àwọn ohun ìtìjú tí ó nfa ìdibàjẹ́, tí ó ńdúró níbi tí kò ti yẹ, jẹ́ kí àwọn tí ó wà ní Jùdíà sáré lọ sí orí òkè, 15 jẹ́ kí ẹni tí ó wà lórí ilé má ṣe lọ inú ilé tàbí mú ohunkóhun kúrò nínú rẹ̀, 16 ati ẹni ti o wà ní oko máṣe páda wá sí ilé mú aṣọ. 17 Ṣùgbọ́n ègbé ni fún àwọn tó gbé ọmọ àti àwọn tó ńtọ́jú ọmọ ọwọ́ ní àwọn ọjọ́ náà. 18 Ẹ gbàdúra pe kí èyí má ṣẹlẹ̀ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. 19 Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò ti i ṣẹlẹ̀ ri láti àsìkò, ti Ọlọ́run dá ayé, títí di òní, rárá, tàbí tí yóò tùń ṣẹlẹ̀ mọ́. 20 Àyàfi bí Olúwa bá dín ọjọ́ náà kù, kò sí ẹni tí yóò yè. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn àyànfẹ́, àwọn tí ó yàn, ó ti gé àwọn ọjọ́ náà kúrú. 21 Nígbànáà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fùn un yín pé, 'wò ó, èyí ni Krísìtì náà!' Wò ó, níbìyí ló wà! má ṣe gbàágbọ́. 22 Nítorí èké Krístì àti èké wòlíì yóò farahàn, nwọ̀n o si fi àmìn àti iṣẹ́-ìyanu han, láti le tanni, tí ó bá ṣeéṣe, àwọn àyànfẹ́ náà pèlú. 23 Ẹ wà ní ìṣọ́ra! Èmí ti ńsọ ǹkan wọ̀nyí fún yín ṣáájú àkokò náà. 24 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìpọ́njú àwọn ọjọ́ náà, oòrùn yio ṣóòkùn, òṣùpá kì yíò tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, 25 àwọn ìrawọ̀ yio jábọ́ lati òkè, àti àwọn agbára ti o wà lọ́run yíó mì. 26 Nígbànáà ni nwọ́n o rí Ọmọ Ènìyàn tí ó ǹsọ̀kalẹ̀ láti inú àwọọ́sánmọ̀n pèlú agbára àti ògo. 27 Nígbànáà ni yíò ràń àwọn ángẹ́lì rẹ̀, yio si ko àwọn àyànfẹ́ rẹ lati inú orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, láti òpin ayé títí dé òpin àwọọ́sánmọ̀n. 28 Kọ́ ẹ̀kọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Ni kété tí ẹ̀ka rẹ̀ bá ti yọ, tí ó rúwé, ẹ̀yin yíó mọ̀ pè ìgbà òjò ti súnmọ́. 29 Bákań náà, nígbàtí ẹ bá ńrí ǹkan wọ̀nyí tí ó ńṣẹlẹ̀, ẹ̀yin yóò mọ̀ pe Ó sún mọ́ etílé, Ó wà nítòsí. 30 Nítòótó, mo sọ fún un yín, ìran yí kò ní kọjá lọ títí gbogbo ǹkan wọ̀nyi yóò fi wá sí ìmúṣẹ. 31 Ọ̀run àti ayé yíò kọjá lọ, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ mi kì yóò kọjá. 32 Ṣùgbọ́n nípa ọjọ́ náà tàbí wákàtí náà, ẹ́nìkan kò mọ̀, kódà àwọn ángélì, tàbí Ọmọ, bíkòṣe Baba nìkan ní ò mọ̀. 33 Ẹ kíyèsára! Ẹ ṣọ́nà, nítorí ẹ kò mọ àkokò tí yíò jẹ̀ ẹ́. 34 Ó dàbí ọkùnrin kan tí ó n lọ sí ìrìnàjò- ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, o si fi ọmọọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe àbojútó ilé rẹ̀, enikọ̀ọ̀kan pẹ̀lú iṣẹ́ rẹ̀, o si pàṣẹ fún aṣọ́nà kí ó ma sùn. 35 Nítorínà, ẹ kíyèsára nítorí ẹ kò mọ àsìkò tí olórí ilé yóò padà wá ilé; ó le jẹ́ ìrọ̀lẹ́, tàbí ní àárín òru, tabi ní àfẹ̀mọ́jú, tàbí ní òwúrọ̀. 36 Bí ó bá dé lójijì, máṣe jẹ́ kí ó bá ọ nínú oorun. 37 Oun tí mo sọ fún ọ, na ni mo sọ fún gbogbo ènìyàn. Ẹ ṣọ́nà!"

Chapter 14

1 Ó ku ọjọ́ méjì sí àjọ ìrékọjá àti àjọ àíwúkárà. Àwọn olórí àlúfà àti akọ̀wé ń ro bí wọn yí ò ti rora mú Jésù láì fura kí wọn sí pá. 2 Nítorí wón ń sọ wípé, "Kìí se nígbà ọdún, kí rúkèrúdò má baà sẹlẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn. 3 Nígbàtí Jésù wà ní Bẹ́tánì ní ilé Símónì adẹ́tẹ̀, bí ó ti jókǒ ní tábílì, obìnrin kan tí ó ní ìgò alabástà òróró iyebíye, tí ó jẹ́ aláìlábáwọn nérdì. Ó fọ́ ìgò náà ó sì dàá si ní orí. 4 Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bínú. Wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ láàrín ara wọn, wọn sì wípé, "Kí ni ìdí tí a se fi òróró yi sòfò? 5 A kò bá ti ta òróró ìkunra dídùn yí ní ọ̀dúńrún dénárì, kí á sí fún àwọn aláìní." Wọ́n sí bá obìnrin náà wí. 6 Ṣùgbọ́n Jesu wípé, "Ẹ jọ̀wọ́ rẹ̀. Kílódé tí ẹ̀yin fi ń ba a wí? Ó ti se ohun dídára fún mi. 7 Nígbà gbogbo ní ẹ̀yin ní tálákà pẹ̀lú yín, ẹ̀yin sì le se oore fún wọn nígbà tí ó bá wù yín, ṣùgbọ́n èmi ni ẹ̀yin kó ní nígbà gbogbo. 8 Ó ti ṣe èyí tí ó le ṣe: ó ti fi òróró kùn ara mi fún ìsìnkú mi. 9 Lótǐtó ni mo wí fun yín, níbikíbi tí a ó gbé wàásù ìhìnrere ní gbogbo aiyé, a ó sì sọ̀rọ̀ ohun tí obìnrín yǐ ṣe ní ìrántí rẹ̀. 10 Nígbànáà ni Júdásì Iskariotu, ọ̀kan nínú àwọn méjìlà, sì tọ̀ àwọn olóri àlúfà lọ láti fàá le wọn lọ́wọ́. 11 Nígbàtí àwọn olórí àlùfáà sì gbọ́ èyi, wọ́n yọ̀, wọ́n sì ṣe ìlérí láti fún n ní owó. Ó sì ń wá ọ̀nà láti fi lé wọn lọ́wọ́. 12 Ní ọjọ́ kínǐ àjọ àìwúkárà, nígbàtí wọ́n pa ẹran ìrékọjà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wí fún n pé, "Níbo ni ìwọ fẹ́ kí á lọ pèsè sílẹ̀, kí ìwọ́ kí ó le jẹ ìrékọjá. 13 Ó sì rán méjì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yin ó sì wí fún wọn pé, "E lọ sí iń ìlú, okùnrin tí ń ru 777 omi yíò pàde yín. Ẹ tẹ̀lẹ́ e. 14 NÍbití ó bá ti wọlé, ẹ tẹ̀lé e kí ẹ sì wí fún onílé wípé, 'Olùkọ́ni wípé, "NÍbo ni yàrá ìgbàlejò tí èmi yíò ti jẹ ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ èyìn mi?" 15 Ò n ó sì fi gbọ̀ngàn ńlá kan tí a ti se lọ́sọ̌ lókè hàn yín tí a ti pèsè sílè. Níbẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó pèsẹ̀ sílẹ̀ fún wa. 16 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì jáde lọ sí ìlú. Wọ́n sì rí i gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún wọn, wọ́n sì pèsè ìrékọjá sílẹ̀. 17 Nígbàtí alẹ́ lẹ́, ó wá pẹ̀lú àwọn méjìlá. 18 Bí wọ́n sì ti jókǒ tí wọ́n ń jẹun, Jésù wípé, "Lõtọ ni mo wí fún n yín, ọ̀kan nínú yín tí ó ń bá mi jẹun yíò fi mí hàn. 19 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kãnú gidigidi, wọ́n sì ń bi ra wọn léérè lẽre lọ́kọ̃kan wípé, "Èmi ni bí? 20 Jésù sí dáhùn ó sì wí fún wọn pé, "Ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, tí ó ń tọwọ́ bọ̀ inú àwo pẹ̀lu mi. 21 Nítòótọ́ Ọmọ ènìyàn yíò lọ bí a ti kọ̀wé nípa tirẹ̀. Ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin nâ tí yíò jé sábàbí ìdàlè Ọmọ ènìyàn! ìbá sàn fún ọkùnrin náà tí a kò bá bí sáyé rárá. 22 Bí wọ́n sì ti ń jẹun, Jésù mú àkàrà, ó sì súre, ó sì pínn. Ó sì fifún wọn ó wípé, "Gba èyí. Èyí ni ara mi. 23 Ó sì gbé àgò, ó dúpẹ́, ó sì fifún wọn, gbogbo wọ́n sì mu nínú rẹ̀. 24 Ó wí fún wọn pé, "Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi ti májẹ̀mú, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ èniyàn. 25 Lõtọ ni mo wí fu]n n yín, èmi kì yíò mu nínú èso àjàrà mọ́, títí yíò fi di ọjọ́ nà nígbàtí èmi ó muú ní titun ní ìjọba Ọlọ́run 26 Nígbàtí wọ́n ti kọ orin kan, wọ́n jáde lọ sí orí òkè Òlìfí. 27 Jésu wí fún wọn pé, " Gbogbo yín ni yíò kọsẹ̀, nítorítí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé, 'Èmi ó lù olùṣọ́ àgùntàn agbo agùntàn yíò sì túká. 28 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí mo bá jí dìde, èmi ó ṣájúu yín lọ sí Galili. 29 Peteru wí fún u pé, "Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ kọsẹ̀, èmi kì yó kọsè." 30 Jésù wí fún u pé, "Lõtọ ni mo wí fún ọ, lásǎlẹ́ yi, kí àkùkọ kí ó tó kọ nígbà méjì, ìwọ ô kò mí nígba mẹ́ta. 31 Ṣùgbọ́n Pétérù wípé, "Bí ó bá jẹ́ ti ikú pẹ̀lú rẹ, èmi kò ní sẹ́ ọ." Gbogbo wọ́n sì jẹ́jẹ̌ kannáà. 32 Wón sì wá sí ibi kàn tí à ńpè ní Gẹ́tsímánì, ó sì wí fún àwọn ọmọ èyìn rẹ̀ pé, "Ẹ jókǒ ní ìhín nígbàtí mo bá lọ gbàdúrà. 33 Ó sì mú Pétérù àti Jákọ́bù àti Jòhánù pẹ̀lú rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ́ sí ní ìrẹ̀wẹ̀sí ọkàn, ọkàn rẹ̀ sì dàrú gidigidi. 34 Ó sì wí fún wọn pé, "Ọkàn mi ńkãnu gidigidi, títí dé ojú ikú. Ẹ dúró níhǐn kí ẹ sì mã ṣọ́nà. 35 Jésù sí lọ síwájú díẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀, ó sì gbàdúrà pé, bí ó bá se é se, kí wákàtí yìí ré kọjá kúrò lórí rẹ̀. 36 Ó wípé, "Abba, Bàbá, ohun gbogbo ni síse fún ọ. Mú ago yìí kúrò lórí mi. ṣùgbọ́n kì íṣe ti ìfẹ́ mi, bíkòse ti ìwọ." 37 Ó padà wá, ó sì rí wọn tí wón n sùn, ó sì wí fún Pétérù, "Símónì, ìwọ ń sùn bi? Ìwọ kò ha le sọ́nà fún wákàtí kan? 38 Ẹ máa sọ́nà kí e sì ma gbàdúrà kí ẹ̀yin kí ó má baà bọ́ sínú ìdánwò. Ẹ̀mí ń fẹ́ nítòótọ́, ṣùgbọ́n ó se àìlera fún ara." 39 Ó sì tún lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ wọn láti lọ gbàdúrà, ó sì tún lo ọ̀rọ̀ kanńà. 40 Ó sì tún bá wọn tí wọn ń sùn, nítorí tí ojú wọn wúwo wọn kó sí mọ ohun tí wọn yí ò sọ fún n. 41 Ó sì wá ní ìgbà kẹta ó sì wí fún wọn pé, " Sé ẹ̀yin sí n sùn ni? Ó ti tó! Wákàtí náà ti dé. Wò ó! Ati fi ọmọ ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́sẹ̀ lọ́wọ́. 42 Ẹ dìde; ẹ jẹ́kí á lọ. Wó ò, ẹni tí yíò dà mí ti wà nítòsí." 43 Nígbàtí ó sì ń sọ̀rọ̀, Júdásì, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá, dé, ọ̀pọ̀ ènìyàn sí wà pẹ̀lú rẹ̀ pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀, láti ọ̀dọ̀ olórí àlúfà, àwọn akòwé, àti àwọn àgbà. 44 Ẹni tí yí ò dà á ti fún wọn ní àmì, wípé, " Ẹnikẹ́ni tí òun bá fi ẹnu kò ní ẹnu, òun ni. Ẹ mú u lọ." 45 Nígbàtí Júdásì sì dé, lójúkanńà ó tọ Jésù wá ó sì wípé, "Olùkọ́," ó sì fi ẹnu kò ó ní ẹnu. 46 Wọ́n sì mú u. 47 Ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn tí ó sún mọ́ wọn yọ idà rẹ̀ ó sì fi gé etí ọmọ-ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà. 48 Jésù sì wí fún wọn pé, "Sé ẹ̀yin jáde wá gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó fé mú olè ni, pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ láti wá mú mi? 49 Nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín nígbà gbogbo tí mo sì ń kọ́ọ yín ní témpílì, ẹ̀yin kò mú mi. Ṣùgbọ́n a se èyí kí á le mú ọ̀rọ̀-mímọ́ sẹ." 50 gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lu Jésù sì fií sílẹ̀ wọ́n sì sá lọ. 51 Ọmọkùnrin kan, tí ó fi asọ ọ̀gbọ̀ nìkan wé ara rẹ̀, sì ń tẹ̀lẹ́ Jésù. Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà sì mú Jésù. 52 Ó fi asọ ọ̀gbọ̀ náà sílẹ̀, ó sì sá kúrò ní ìhòhò. 53 Wọ́n sì mú Jẹ́sù lọ ṣọ́dọ̀ olórí àlùfáà. Gbogbo àwọn olórí àlùfàà, àti àwọn àgbàgbà, àti àwọn akọ̀wé sì péjọ pẹ̀lú rẹ̀. 54 Pétérù sì n tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè wọ̀ inú ilé, títí wọ́n fi dé àgbàlá olóri àlùfáà. Ó sì bá àwọn ẹ̀sọ́ jókǒ, tí wọ́n ń yáná. 55 Nígbànáà ni àwọn olórí àlùfá àti gbogbo àjọ ìgbìmọ̀ júù ńwá ẹ̀rí lòdì sí Jésù láti pa á. Wọn kò sì rí ohun kan. 56 Nítorípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó jẹ́rìí èké sí i, ṣùgbọ́n ohùn àwọn ẹlẹ́rǐ náà kò ṣọ̀kan. 57 Àwọn kan sì dìde, wọ́n ń jẹ́rǐ èké sí i; wọ́n wípé, 58 "Àwa gbọ́ tí ó ún sọ wípé, Èmi ó wó tẹ́mpìlì yí tí a fi ọwọ́ ṣe, ní wọ̀n ijọ́ mẹ́ta èmi ó sì kọ́ òmíràn tì a kò fi ọwọ́ se." 59 Síbẹ̀ ẹ̀rí wọn kò sọ̀kan. 60 Olórí àlùfáà sì dìde láarín wọn ó sì bi Jésù lêrè wípé, Ìwọ kò ní ìdáhùn bí, kíni ohun tí àwọn ènìyàn yín jẹ́rǐ lòdì sí ọ? 61 Ó sì dákẹ́, kò sì so ohunkóhun. Olórí àlùfáà sì bií lêrè wípé, "sé ìwọ ni Krístì ọmọ olùbùkún?" 62 Jésù wípé, "Èmi ni; ìwọ yíò sì rí ọmọ Ènìyàn nígbàtì ó bá jókǒ ní apá ọ̀tún agbára tí ó sì wà ní àwọ sánmọ̀." 63 Olórí àlùfáà sì fa asọ rẹ̀ ya ó sì wípe, "Sé a sì nílò ẹlẹ́rǐ bí? 64 Ẹ̀yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn náà. Kíni ìpinu yín? Gbogbo wọn sì kẹ́gàn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí ó yẹ fún ikú. 65 Àwọn míràn bẹ̀rẹ̀ sí ní tutọ́ síi lára wọ́n sì bo ojú rẹ̀ wọ́n sì lû wọ́n wí fun pé, "sọtẹ́lẹ̀!" Àwọn ọmọ ogun sì mú wọ́n sì lùú. 66 Bí Pétérù sì ti wà ní ìsàlẹ̀ ní àafin, ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin olórí àlùfáà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. 67 Ó rí Pétérù tí ó ńyáná, ó tẹjú mọ́ ọ, ó sì wípe, ìwọ́ wà pẹ̀lú Jésù aráa Násárẹ́tì yí. 68 Ṣùgbọ́n ó sẹ́ ẹ, ó wípé, "Èmi kò mó bẹ́ẹ̀ni òye ohun tí ìwọ ńsọ kò tilẹ̀ yé mi." Ó sì jáde lọ sí àgbàlá. Àkùkọ sì kọ. 69 Ọmọbìnrin nǎ sì tún rí i, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ fún àwọn tí ó dúró níbẹ̀ pẹ́, "Ọ̀kan nínú wọn ni okùnrin yî. 70 Ó sì tún sẹ́ ẹ. Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, àwọn tí ó dúró níbẹ̀ tún wí fún Pétérù pé, "Lóòtọ́ ni, ọ̀kan nínú wọn ní ìwọ íṣe, nítorípé ará Gálílì ni ìwọ náà. 71 Ṣùgbọ́n ọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ara rẹ̀ ré ó sì búra wípé, "Èmi kò mọ ọkùnrín yǐ tí ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀." 72 Lójúkańnà àkùkọ sì kọ ní ìgbà kejì. Pétérù sí rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù wí fún u pé: "Kí àkùkọ kí ó tó kọ lẹ́ẹ̀mejì , ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹta." ó bara jẹ́, ó sì sọkún.

Chapter 15

1 Ní àárọ̀ kùtùkùtù, àwọn olórí àlúfàà pàdé pẹ̀lú àwọn àgbààgbà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé àti gbogbo ìgbìmọ̀ àwọn Júù. Lẹ́yìn náà ni wọ́n so Jésù, wọ́n sì múu lọ. Wọ́n fi lé Pílátù lọ́wó. 2 Pílátù bií, "Sé ìwọ ni ọba àwọn Júù bí?" Ó dáalóhùn, "Ìwọ́ wí." 3 Àwọn olórí àlùfáà ń fi ẹ̀sùn púpọ̀ kan Jésù. 4 Pílátù tún bií léèrè, "Ìwọ kò ní ìdáhùn ni? Wo iye àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn ọ́!" 5 Sùgbọ́n Jésù kò dá Pílátù lóhùn mọ́, èyí sì yàá ní ẹnu. 6 Nísinsnìyí ni àsìkò àsè, Pílátù máa ń fi ẹlẹ́wọ̀n kan lé wọn lọ́wọ́, ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n bá béèrè. 7 Ní ibẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọlọ́tẹ̀ nínu túbú, láàrin àwọn apànìyàn tí ó lọ́wọ́ nínú ọ̀tẹ̀, ni ọkùnrin tí à ń pè ní Bárábà wà. 8 Àwọn èrò náà wá sí ọ̀dọ̀ Pílátù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bi léèrè pé kí ó se oun tí ó tí n se tẹ́lẹ̀ fún wọn. 9 Pílátù dáwọn lóhùn wípé, "Ǹjẹ́ ẹ̀yin fẹ́ kí èmi fi Ọba àwọn Júù lé e yín lọ́wọ́ bi?" 10 Nítorí ó mọ̀ pé àwọn olórí àlùfáà fi Jésù lé òun lọ́wọ́ nítorí owú ni 11 Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà ru àwọn èrò sókè láti pariwo pé Baraba ni kí ó fi sílẹ̀ (ẹ̀wẹ̀). 12 Pílátù sì tún dáwọn lóhùn wípé, "Kíni kí èmi kí ó se fún Ọba àwọn Júù nígbànáà?" 13 Wọn sì tún pariwo, "Kàn-án mọ́ àgbélèbú" 14 Pílátù sì wí fún wọn, "Kíni àìda tó se?" Sùgbọ́n wọ́n tún pariwo sókè síi, "Kàn-án mọ́ àgbélèbú." 15 Pílátù fẹ́ tẹ́ àwọn èrò náà lọ́rùn, nítorínà, ó fi Bárábà sílẹ̀ fún wọn. Ósì naa Jésù, lẹ́yìn náà ó fi lé wọn lọ́wọ́ láti kà-án mọ́ àgbélèbú. 16 Àwọn ọmọ ogun sì múu wọ inú ilé ẹjọ (èyí tí ńse olú ilé-iṣẹ́ ìjọba), wọ́n sì pe gbogbo àwọn ọmọ ogun ìyókù 17 Wọ́n fi asọ ìgúnwà elése àlùkò wọ̀ọ́, wọ́n sì hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dée ní orí 18 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí júbà rẹ̀ pé "Ìbà o, Ọba àwọn Júù!" 19 Wọ́n lu orì rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pá wọ́n sì tu itọ́ síi lára. Wọ́n kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀ bíì pé wón júbà rè. 20 Nígbàtí wọ́n ti fi se ẹlẹ́yà tán, wọ́n bọ́ asọ ìgúnwà elése àlùkò náà wọ́n sì fi asọ rẹ̀ wọ̀ọ́, wón sì múu lọ láti kàán mọ́ àgbélèbú 21 Wọ́n fi ipá mú ẹnìkan tó n kọjá lọ lẹ́bàá ọ̀nà láti gbé àgbélèbú Jésù, ọkùnrin tí à n pé orúkọ rẹ̀ ní Símónì ará Kírénì, bàbá Alesándérù àti Rúfọ́sì. 22 Àwọn ọmọ ogun náà mú Jésù lọ sí ibi tí à ńpè ní Gọ́lgọ́tà (èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ ńjẹ́, "Ibi agbárí"). 23 Wọ́n fun ní wáínì tí a pò pẹ̀lú òjìá, ṣùgbọ́n kò muú 24 Wón Kàn-án mọ́ àgbélèbú nígbàtí wọ́n sì sẹ́ gègé láti pín asọ rẹ̀ láàrin ara wọn. 25 Ójẹ́ wákàtí kẹẹ̀ta ọjọ́ nigbàtí wọ́n kà-án mọ́ àgbélèbú 26 Wọ́n kọ ẹ̀sùn rẹ̀ sí orí pátákó kan pé, "Ọba àwọn júù." 27 Wọ̀n kàn-án mọ́ àgbélèbú pẹ̀lú olè mèjí, ìkan ní ọwọ́ ọ̀tún àti ìkan ní ọwọ́ òsì 28 "Amú ìwé mímọ́ náà ṣẹ pé, 'Akàá pẹ̀lú àwọn arúfin.' 29 Àwọn tó n kọjá lọ búu, wọ́n mi orí wọn wọ́n sì wípé, "Áha! Ìwọ́ tó fẹ́ wó tẹ́mpìlì kí osì tún kọ láàrin ọjọ́ mẹta, 30 gba ara rẹlà ki osì sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélèbú!" 31 Bàkanáà ni àwọn olórí àlàfáà ńse ẹlẹ́yà rẹ̀ láàrín ara wọn, pẹ̀lú àwọn akọ̀wé, wọ́n sì wípé, "Ó gba àwọn míràn là sùgbọ́n kò lè gba ara rẹ̀. 32 Jẹ́kí Krístì náà, Ọba Ísrẹ́ẹ́lì náà, sọ̀kalẹ̀ nísinsìnyí láti orí àgbélèbú, kí àwá lè ríi, kí à sì gbàgbọ́," àwọn tí a kàn mọ́ àgbélèbú pẹ̀lú rẹ̀ náà sì kẹ́gàn rẹ̀. 33 Nígbàtí ó di wákàtí kẹfà ọjọ̀, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹẹ̀sán 34 Ní ìgbà tí ó di wákàtí kẹẹ̀sán, Jésù pariwo ní ohùn rara, "Eloi, Eloi, lama sabachthani?" èyí tí ó túmọ̀ sí "Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, kílódé tí ìwọ́ fi kọ̀ mí sílẹ̀?" 35 Àwọn tí ó dúró gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n sì wípé, "wòó, óún pe Èlíjà" 36 Ẹnìkan sáré láti fí ọtí kíkan sí orí fùkẹ̀fùkẹ̀, wón fi sí orí ọ̀pá, wọ́n sì fi fun láti mu. Ọkùnrin náà wípé, "Ẹjẹ́ kí á wòó bóyá Èlíjà yó wá múu sọ̀kalẹ̀." 37 Jésù sì kígbe lóhùn rara, ósì kú 38 Asọ ìkéle tẹ́mpílí sì fàya sí méjì láti òkè títí dé ìsàlẹ̀. 39 Nígbàtí Ọ̀gágun ọgọ̀rún tí ó dúró kojú sí Jésù ri pé ó ti kú, ó wípé, "Nítòótọ́, ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yíí." 40 Àwọn obìnirin tí n wò láti ọ̀kánkán wànì ibẹ̀. Nínú wọn ni Maria Magdaleni, Maria (ìya Jákọ́bù kékerè àti Jósè), àti Sàlómì. 41 Nígbàtí ó wà ní Galili, wọ́n tẹ̀le láti sìn. Àwọn obìnrin míràn sì tẹ̀lee wá sí Jerusalemu pẹ̀lú. 42 Nígbàtí alẹ́ dé, nítorípé ó jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ fún Sábátì 43 Jósẹ́fù ará Arimatia wá síbẹ̀. Ó jẹ́ ènìyàn pàtàkì nínú ìgbìmọ̀ tó ń dúró de ìjọba Ọlọ́run. Ó lọ sí ọ̀dọ Pílátù pẹ̀lù ìgboyà láti bèrè fún ara Jésù. 44 Ẹnú ya Pílátù pé Jésù ti kú; ó pe ògágun-ọgọ̀rún láti bií bóyá Jésù ti kú. 45 Nígbàtí Pílátù gbọ́ láti ọ̀dọ ọ̀gágun-ọgọ̀rún pé Jésù ti kú, ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún Jósẹ́fù 46 Jóséfù sì ti ra asọ dídán kan. Ó gbe sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélèbú, ó fi asọ náà wée, ó sì tẹ sí inú ibojì tí a ti gbẹ́ nínú àpáta. Nígbà náà, ó yí òkúta sí ẹnu ọ̀nà ibojì náà 47 Maria Magdaleni àti Maria ìya Jósè sì rí ibi tí a sin Jésù sí.