Yorùbá (Yoruba): Biblica Open Yoruba Contemporary Bible

Updated ? hours ago # views See on DCS

Ẹkún Jeremiah

Chapter 1

     1 Báwo ni ìlú ṣe jókòó nìkan,

         nígbà kan tí ó sì kún fún ènìyàn!

     Ó ti fìgbà kan jẹ́ ìlú olókìkí láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,

         tí ó wà ní ipò opó,

     ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọbabìnrin láàrín ìlú

         ni ó padà di ẹrú.

 

     2 Ọ̀gànjọ́ òru ni ó fi máa ń sọkún kíkorò

         pẹ̀lú omijé ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ tí ó dúró sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀.

     Nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀

         kò sí ọ̀kan nínú wọn láti rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún.

     Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti jọ̀wọ́ rẹ̀

         wọ́n ti di alátakò rẹ̀.

 

     3 Lẹ́yìn ìjìyà àti ìpọ́njú nínú oko ẹrú,

         Juda lọ sí àjò

     Ó tẹ̀dó láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,

         ṣùgbọ́n kò rí ibi ìsinmi.

     Àwọn tí ó ń tẹ̀lé ká á mọ́

         ibi tí kò ti le sá àsálà.

 

     4 Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Sioni ń ṣọ̀fọ̀,

         nítorí ẹnìkan kò wá sí àjọ̀dún tí a yàn.

     Gbogbo ẹnu-bodè rẹ̀ dahoro,

         àwọn àlùfáà rẹ̀ kẹ́dùn,

     àwọn wúńdíá rẹ̀ sì ń káàánú,

         òun gan an wà ní ọkàn kíkorò.

 

     5 Àwọn aninilára rẹ̀ gbogbo di olúwa rẹ̀,

         nǹkan sì rọrùn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀,

     Olúwa ti fún un ní ìjìyà tó tọ́

         nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

     Àwọn ẹ̀ṣọ́ wẹ́wẹ́ rẹ̀ lọ sí oko ẹrú,

         ìgbèkùn níwájú àwọn ọ̀tá.

 

     6 Gbogbo ẹwà ti di ohun ìgbàgbé

         kúrò lọ́dọ̀ ọmọbìnrin Sioni.

         Àwọn ìjòyè rẹ̀ dàbí i àgbọ̀nrín

     tí kò rí ewé tútù jẹ;

         nínú àárẹ̀ wọ́n sáré

     níwájú ẹni tí ó ń lé wọn.

 

     7 Ní ọjọ́ ìpọ́njú àti àrìnká rẹ̀ ni

         Jerusalẹmu rántí àwọn ohun ìní dáradára rẹ̀

         tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́.

     Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú ṣọ́wọ́ àwọn ọ̀tá,

         kò sì ṣí olùrànlọ́wọ́ fún un.

     Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wò ó

         wọ́n sì ń fi ìparun rẹ̀ ṣẹlẹ́yà.

 

     8 Jerusalẹmu sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀

         ó sì ti di aláìmọ́.

     Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀,

         nítorí wọ́n ti rí ìhòhò rẹ̀;

     ó kérora fúnra rẹ̀,

         ó sì lọ kúrò.

 

     9 Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀,

         bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀.

     Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu;

         olùtùnú kò sì ṣí fún un.

     “Wo ìpọ́njú mi, Olúwa ,

         nítorí àwọn ọ̀tá ti borí.”

 

     10 Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ lé

         gbogbo ìní rẹ;

     o rí pé àwọn orílẹ̀-èdè

         tí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ—

     àwọn tí o ti kọ̀sílẹ̀

         láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ.

 

     11 Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérora

         bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ;

     wọ́n fi ohun ìní wọn ṣe pàṣípàrọ̀ oúnjẹ

         láti mú wọn wà láààyè.

     “Wò ó, Olúwa , kí o sì rò ó,

         nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.”

 

     12 “Kò ha jẹ́ nǹkan kan sí i yín?

         Gbogbo ẹ̀yin tí ń rékọjá.

     Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyà

         tí a fi fún mi, ti

     Olúwa mú wá fún mi

         ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀.

 

     13 “Ó rán iná láti òkè

         sọ̀kalẹ̀ sínú egungun ara mi.

     Ó dẹ àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi,

         ó sì yí mi padà.

     Ó ti pa mí lára

         mó ń kú lọ ní gbogbo ọjọ́.

 

     14 “Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti di sísopọ̀ sí àjàgà;

         ọwọ́ rẹ̀ ni a fi hun ún papọ̀.

     Wọ́n ti yí ọrùn mi ká

         Olúwa sì ti dín agbára mi kù.

     Ó sì ti fi mí lé

         àwọn tí n kò le dojúkọ lọ́wọ́.

 

     15 “Olúwa kọ

         àwọn akọni mi sílẹ̀,

     ó rán àwọn ológun lòdì sí mi

         kí wọn pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi run.

     Nínú ìfúntí wáìnì rẹ̀ Olúwa tẹ́

         àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Juda.

 

     16 “Ìdí nìyí tí mo fi ń sọkún

         tí omijé sì ń dà lójú mi.

     Olùtùnú àti ẹni tí ó le mú ọkàn mi sọjí jìnnà sí mi,

         kò sí ẹni tí yóò dá ẹ̀mí mi padà.

     Àwọn ọmọ mi di aláìní

         nítorí ọ̀tá ti borí.”

 

     17 Sioni na ọwọ́ jáde,

         ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un.

     Olúwa ti pàṣẹ fún Jakọbu

         pé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀tá fún un

     Jerusalẹmu ti di

         ohun aláìmọ́ láàrín wọn.

 

     18 “Olóòtítọ́ ni Olúwa ,

         ṣùgbọ́n mo ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀.

     Ẹ gbọ́, gbogbo ènìyàn;

         ẹ wò mí wò ìyà mi.

     Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi

         ni a ti kó lọ sí ìgbèkùn.

 

     19 “Mo pe àwọn ọ̀rẹ́ mi

         ṣùgbọ́n wọ́n dà mí.

     Àwọn olórí àlùfáà àti àgbàgbà mi

         ṣègbé sínú ìlú

     nígbà tí wọ́n ń wá oúnjẹ

         tí yóò mú wọn wà láààyè.

 

     20 Olúwa , wò ó, bí mo ti wà nínú ìnira!

         Tí mo sì ń jẹ̀rora nínú mi,

     ìdààmú dé bá ọkàn mi

         nítorí pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi gidigidi.

     Ní gbangba ni idà ń parun;

         ikú wà nínú ilé pẹ̀lú.

 

     21 “Àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìrora mi,

         ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún mi.

     Àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ ìparun mi;

         wọ́n yọ̀ sí ohun tí o ṣe.

     Kí o mú ọjọ́ tí o ti kéde,

         kí wọ́n le dàbí tèmi.

 

     22 “Jẹ́ kí ìwà ìkà wọn wá síwájú rẹ;

         jẹ wọ́n ní yà

     bí o ṣe jẹ mí ní yà

         nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi.

     Ìrora mi pọ̀

         ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.”

 

 

Chapter 2

     1 Báwo ni Olúwa ṣe bo ọmọbìnrin Sioni

         pẹ̀lú àwọsánmọ̀ ìbínú rẹ̀!

     Ó sọ ògo Israẹli kalẹ̀,

         láti ọ̀run sí ayé;

     kò rántí àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀

         ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀.

 

     2 Láìní àánú ni Olúwa gbé

         ibùgbé Jakọbu mì;

     nínú ìrunú rẹ̀, ni ó wó

         ibi gíga ọmọbìnrin Juda lulẹ̀.

     Ó ti mú ìjọba àti àwọn ọmọ-aládé ọkùnrin

         lọ sínú ilẹ̀ ní àìlọ́wọ̀.

 

     3 Ní ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó ké

         gbogbo ìwo Israẹli.

     Ó ti mú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò

         nígbà tí àwọn ọ̀tá dé.

     Ó run ní Jakọbu bí ọ̀wọ́-iná

         ní àgọ́ àwọn ọmọbìnrin Sioni.

 

     4 Ó na ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá;

         ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sì múra.

     Bí ti ọ̀tá tí ó ti parun

         ó tú ìbínú rẹ̀ jáde bí iná

     sórí àgọ́ ọmọbìnrin Sioni.

 

     5 Olúwa dàbí ọ̀tá;

         ó gbé Israẹli mì.

     Ó ti gbé gbogbo ààfin rẹ̀ mì

         ó pa ibi gíga rẹ̀ run.

     Ó sọ ìmí ẹ̀dùn àti ìbànújẹ́ di púpọ̀

         fún àwọn ọmọbìnrin Juda.

 

     6 Ó mú ìparun bá ibi mímọ́,

         ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run.

     Olúwa ti mú Sioni gbàgbé

         àjọ̀dún tí a yàn àti ọ̀sẹ̀ tí ó yàn;

     nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó run

         ọba àti olórí àlùfáà.

 

     7 Olúwa ti kọ̀ pẹpẹ rẹ̀ sílẹ̀

         ó sì ti kọ̀ ibi mímọ́ rẹ̀.

     Ó sì fi lé ọ̀tá lọ́wọ́

         àwọn odi ààfin rẹ̀;

     wọ́n sì kígbe ní ilé Olúwa

         gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àpèjẹ tí a yàn.

 

     8 Olúwa pinnu láti fa

         ògiri tí ó yí ọmọbìnrin Sioni ya.

     Ó gbé wọn sórí òsùwọ̀n,

         kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn.

     Ó mú kí ilé ìṣọ́ àti odi rẹ̀ ṣọ̀fọ̀

         wọ́n ṣòfò papọ̀.

 

     9 Ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀;

         òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́.

     Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,

         kò sí òfin mọ́,

     àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí

         ìran láti ọ̀dọ̀ Olúwa mọ́.

 

     10 Àwọn àgbàgbà ọmọbìnrin Sioni

         jókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́;

     wọ́n da eruku sí orí wọn

         wọ́n sì wọ aṣọ àkísà.

     Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Jerusalẹmu

         ti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀.

 

     11 Ojú mi kọ̀ láti sọkún,

         mo ń jẹ ìrora nínú mi,

     mo tú ọkàn mi jáde sí ilẹ̀

         nítorí a pa àwọn ènìyàn mí run,

     nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ ọwọ́ ń kú

         ní òpópó ìlú.

 

     12 Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn,

         “Níbo ni ọkà àti wáìnì wà?” Wò ó

     bí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣe

         ní àwọn òpópónà ìlú,

     bí ayé wọn ṣe ń ṣòfò

         láti ọwọ́ ìyá wọn.

 

     13 Kí ni mo le sọ fún ọ?

         Pẹ̀lú kí ni mo lè fi ọ́ wé,

         ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu?

     Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé,

         kí n lè tù ọ́ nínú,

         ìwọ wúńdíá obìnrin Sioni?

     Ọgbẹ́ rẹ jì bí Òkun.

         Ta ni yóò wò ọ́ sàn?

 

     14 Ìran àwọn wòlíì rẹ

         jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n;

     wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn

         tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ.

     Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ

         jẹ́ èké àti ìmúniṣìnà.

 

     15 Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ

         pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí;

     wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọn

         sí ọmọbìnrin Jerusalẹmu:

     “Èyí ha ni ìlú tí à ń pè

         ní àṣepé ẹwà,

         ìdùnnú gbogbo ayé?”

 

     16 Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọn

         gbòòrò sí ọ;

     wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payínkeke

         wọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán.

     Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí;

         tí a sì wá láti rí.”

 

     17 Olúwa ti ṣe ohun tí ó pinnu;

         ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ,

         tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́.

     Ó ti ṣí ọ ní ipò láì láàánú,

         ó fún ọ̀tá ní ìṣẹ́gun lórí rẹ,

         ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga.

 

     18 Ọkàn àwọn ènìyàn

         kígbe jáde sí Olúwa .

     Odi ọmọbìnrin Sioni,

         jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ sàn bí odò

         ní ọ̀sán àti òru;

     má ṣe fi ara rẹ fún ìtura,

         ojú rẹ fún ìsinmi.

 

     19 Dìde, kígbe sókè ní àṣálẹ́,

         bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀

     tú ọkàn rẹ̀ jáde bí omi

         níwájú Olúwa .

     Gbé ọwọ́ yín sókè sí i

         nítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀

     tí ó ń kú lọ nítorí ebi

         ní gbogbo oríta òpópó.

 

     20 “Wò ó, Olúwa , kí o sì rò ó.

         Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyí.

     Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn,

         àwọn ọmọ tí wọn ń ṣe ìtọ́jú fún?

     Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíì

         ní ibi mímọ́ Olúwa ?

 

     21 “Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀

         sínú eruku àwọn òpópó;

     àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi

         ti ṣègbé nípa idà.

     Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ,

         Ìwọ pa wọ́n láìní àánú.

 

     22 “Bí ó ti ṣe ní ọjọ́ àsè,

         bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi ẹ̀rù sí ẹ̀gbẹ́ mi.

     Ní ọjọ́ ìbínú Olúwa

         kò sí ẹni tí ó sálà tí ó sì yè;

     àwọn tí mo ti tọ́jú tí mo sì fẹ́ràn,

         ni ọ̀tá mi parun.”

 

 

Chapter 3

     1 Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njú

         pẹ̀lú ọ̀pá ìbínú rẹ.

     2 Ó ti lé mi jáde ó sì mú mi rìn

         nínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀.

     3 Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ rẹ̀ padà sí mi

         síwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́.

 

     4 Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran-ara mi gbó

         ó sì tún ṣẹ́ egungun mi.

     5 Ó ti fi mí sí ìgbèkùn, ó sì ti yí mi ká

         pẹ̀lú ìkorò àti làálàá.

     6 Ó mú mi gbé nínú òkùnkùn,

         bí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.

 

     7 Ó ti tì mí mọ́ ilé, nítorí náà n kò le è sálọ;

         ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀.

     8 Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́,

         ó kọ àdúrà mi.

     9 Ó fi ògiri òkúta dí ọ̀nà mi;

         ó sì mú ọ̀nà mi wọ́.

 

     10 Bí i beari tí ó dùbúlẹ̀,

         bí i kìnnìún tí ó sá pamọ́.

     11 Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀

         ó fi mi sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́.

     12 Ó fa ọfà rẹ̀ yọ

         ó sì fi mí ṣe ohun ìtafàsí.

 

     13 Ó fa ọkàn mí ya

         pẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.

     14 Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrín àwọn ènìyàn mi;

         wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́.

     15 Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkorò

         àti ìdààmú bí omi.

 

     16 Ó ti fi òkúta kán eyín mi;

         ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.

     17 Mo ti jìnnà sí àlàáfíà;

         mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.

     18 Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọ

         àti ìrètí mi nínú Olúwa .”

 

     19 Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi,

         ìkorò àti ìbànújẹ́.

     20 Mo ṣèrántí wọn,

         ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.

     21 Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkàn

         àti nítorí náà ní mo nírètí.

 

     22 Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé,

         nítorí ti àánú rẹ kì í kùnà.

     23 Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀;

         títóbi ni òdodo rẹ̀.

     24 Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa ;

         nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́.

 

     25 Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀,

         sí àwọn tí ó ń wá a.

     26 Ó dára kí a ní sùúrù

         fún ìgbàlà Olúwa .

     27 Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgà

         nígbà tí ó wà ní èwe.

 

     28 Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́,

         nítorí Olúwa ti fi fún un.

     29 Jẹ́ kí ó bo ojú rẹ̀ sínú eruku—

         ìrètí sì lè wà.

     30 Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a,

         sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.

 

     31 Ènìyàn kò di ìtanù

         lọ́dọ̀ Olúwa títí láé.

     32 Lóòtítọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn,

         nítorí títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.

     33 Nítorí kò mọ̀ ọ́n mọ̀ mú ìpọ́njú wá

         tàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.

 

     34 Láti tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀

         gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà.

     35 Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀

         níwájú Ọ̀gá-ògo jùlọ,

     36 láti yí ìdájọ́ ènìyàn padà,

         ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀.

 

     37 Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀

         tí Olúwa kò bá fi àṣẹ sí i.

     38 Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ

         ni rere àti búburú tí ń wá?

     39 Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè ṣe ń kùn

         nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀?

 

     40 Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò,

         kí a sì tọ Olúwa lọ.

     41 Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè

         sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé,

     42 “Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀

         ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.

 

     43 “Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa;

         ìwọ ń parun láìsí àánú.

     44 Ìwọ ti fi àwọsánmọ̀ bo ara rẹ

         pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ.

     45 Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn

         láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.

 

     46 “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn

         gbòòrò sí wa.

     47 Àwa ti jìyà àti ìparun,

         nínú ìbẹ̀rù àti ewu.”

     48 Omijé ń sàn ní ojú mi bí odò

         nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.

 

     49 Ojú mi kò dá fún omijé,

         láì sinmi,

     50 títí ìgbà tí Olúwa yóò síjú wolẹ̀

         láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.

     51 Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn mi

         nítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi.

 

     52 Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí

         dẹ mí bí ẹyẹ.

     53 Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihò

         wọ́n sì ju òkúta lù mí.

     54 Orí mi kún fún omi,

         mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé.

 

     55 Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa ,

         láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.

     56 Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, “Má ṣe di etí rẹ

         sí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”

     57 O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́,

         o sì wí pé, “Má ṣe bẹ̀rù.”

 

     58 Olúwa , ìwọ gba ẹjọ́ mi rò,

         o ra ẹ̀mí mi padà.

     59 O ti rí i, Olúwa , búburú tí a ṣe sí mi.

         Gba ẹjọ́ mi ró!

     60 Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn,

         gbogbo ìmọ̀ wọn sí mi.

 

     61 Olúwa ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọn

         àti ìmọ̀ búburú wọn sí mi,

     62 ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọ

         sí mi ní gbogbo ọjọ́.

     63 Wò wọ́n! Ní jíjòkòó tàbí ní dídìde,

         wọ́n ń ṣẹlẹ́yà mi nínú orin wọn.

 

     64 Olúwa san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọn

         fún ohun tí ọwọ́ wọn ti ṣe.

     65 Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn,

         kí o sì fi wọ́n ré.

     66 Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú,

         lábẹ́ ọ̀run Olúwa .

 

 

Chapter 4

     1 Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù,

         wúrà dídára di àìdán!

     Òkúta ibi mímọ́ wá túká

         sí oríta gbogbo òpópó.

 

     2 Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Sioni tí ó ṣe iyebíye,

         tí wọ́n fi wúrà dídára ṣe

     wá dàbí ìkòkò amọ̀ lásán

         iṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!

 

     3 Àwọn ajáko pèsè ọmú wọn

         fún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn,

     ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kàn

         bí ògòǹgò ní aginjù.

 

     4 Nítorí òǹgbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́

         lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn;

     àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹ,

         ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó fi fún wọn.

 

     5 Àwọn tí ó ń jẹ ohun dáradára

         di òtòṣì ní òpópó.

     Àwọn tí a fi aṣọ dáradára wọ̀

         ni wọ́n sùn ní orí òkìtì eérú.

 

     6 Ìjìyà àwọn ènìyàn mi

         tóbi ju ti Sodomu lọ,

     tí a sí ní ipò ní òjijì

         láìsí ọwọ́ láti ràn án lọ́wọ́.

 

     7 Ọmọ ọba ọkùnrin wọn mọ́ ju òjò-dídì,

         wọ́n sì funfun ju wàrà lọ

     wọ́n ni ìtọ́jú bí iyùn pupa,

         ìrísí wọn dàbí safire.

 

     8 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n dúdú ju èédú;

         wọn kò sì dá wọn mọ̀ ní òpópó.

     Ara wọn hun mọ́ egungun;

         ó sì gbẹ bí igi gbígbẹ.

 

     9 Àwọn tí ó kù nípasẹ̀ idà sàn

         ju àwọn tí ìyàn pa;

     tí ó wọ àkísà ebi, tí ó ń ṣòfò

         fún àìní oúnjẹ láti inú pápá.

 

     10 Pẹ̀lú ọwọ́ àwọn obìnrin aláàánú

         ni wọ́n ṣe ọmọ wọn jẹ

     tí ó di oúnjẹ fún wọn

         nígbà tí a pa àwọn ènìyàn mi run.

 

     11 Olúwa ti fi ihò kíkún fún ìbínú rẹ̀;

         ó sì tú ìbínú gbígbóná rẹ̀ jáde.

     Ó da iná ní Sioni

         tí ó jó ìpìlẹ̀ rẹ̀ run.

 

     12 Àwọn ọba ayé kò gbàgbọ́,

         tàbí àwọn ènìyàn ayé,

     wí pé àwọn ọ̀tá àti aninilára le wọ

         odi ìlú Jerusalẹmu.

 

     13 Èyí ṣẹlẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn wòlíì

         àti àìṣedéédéé àwọn olórí àlùfáà,

     tí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo

         sílẹ̀ láàrín rẹ̀.

 

     14 Nísinsin yìí wọ́n ń rìn kiri ní òpópó

         bí ọkùnrin tí ó fọ́jú.

     Ẹ̀jẹ̀ ara wọn sọ wọ́n di àbàwọ́n

         tí kò sẹ́ni tó láyà láti fọwọ́ kan aṣọ wọn.

 

     15 “Lọ kúrò! Ẹ̀yin di aláìmọ́!” ni àwọn ènìyàn ń kígbe sí wọn.

         “Ẹ lọ! Ẹ lọ! Ẹ má ṣe fọwọ́ kàn wá!”

     Àwọn ènìyàn láàrín orílẹ̀-èdè wí pé,

         “Wọn kì yóò tẹ̀dó síbí mọ́.”

 

     16 Olúwa ti tú wọn ká fúnra rẹ̀;

         kò sí bojútó wọn mọ́.

     Kò sí ọ̀wọ̀ fún olórí àlùfáà mọ́,

         àti àánú fún àwọn àgbàgbà.

 

     17 Síwájú sí i, ojú wa kùnà

         fún wíwo ìrànlọ́wọ́ asán;

     láti orí ìṣọ́ wa ni à ń wò

         fún orílẹ̀-èdè tí kò le gbà wá là.

 

     18 Wọ́n ń ṣọ́ wa kiri,

         àwa kò sì le rìn ní òpópó wa mọ́.

     Òpin wa ti súnmọ́, ọjọ́ wa sì níye

         nítorí òpin wa ti dé.

 

     19 Àwọn tí ń lé wa yára

         ju idì ojú ọ̀run lọ;

     wọ́n lé wa ní gbogbo orí òkè

         wọ́n sì gẹ̀gùn dè wá ní aginjù.

 

     20 Ẹni àmì òróró Olúwa , èémí ìyè wa,

         ni wọ́n fi tàkúté wọn mú.

     Àwa rò pé lábẹ́ òjìji rẹ̀

         ni àwa yóò máa gbé láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo.

 

     21 Ẹ yọ̀ kí inú yín sì dùn, ẹ̀yin ọmọbìnrin Edomu,

         ẹ̀yin tó ń gbé ní ilẹ̀ Usi.

     Ṣùgbọ́n, a ó gbé ago náà kọjá sọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú;

         ìwọ yóò yó bí ọ̀mùtí, ìwọ yóò sì rìn ní ìhòhò.

 

     22 Ìwọ ọmọbìnrin Sioni, ìjìyà rẹ yóò dópin;

         kò ní mú ìgbèkùn rẹ pẹ́ mọ́.

     Ṣùgbọ́n, ìwọ ọmọbìnrin Edomu, yóò jẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ní yà

         yóò sì fi àìṣedéédéé rẹ hàn kedere.

 

 

Chapter 5

     1 Rántí, Olúwa , ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa;

         wò ó, kí o sì rí ìtìjú wa.

     2 Àwọn ohun ìní wa ti di ti àlejò,

         ilé wa ti di ti àjèjì.

     3 Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba,

         àwọn ìyá wa ti di opó.

     4 A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu;

         igi wa di títà fún wa.

     5 Àwọn tí ó ń lé wa súnmọ́ wa;

         àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.

     6 Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Ejibiti àti Asiria

         láti rí oúnjẹ tó tó jẹ.

     7 Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì ṣí mọ́,

         àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

     8 Àwọn ẹrú ń jẹ ọba lórí wa,

         kò sì ṣí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn.

     9 Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wa

         nítorí idà tí ó wà ní aginjù.

     10 Ẹran-ara wa gbóná bí ààrò,

         ebi sì yó wa bí àárẹ̀.

     11 Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lòpọ̀ ní Sioni,

         àti àwọn wúńdíá ti o wa ní ìlú Juda.

     12 Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di síso sókè ní ọwọ́ wọn;

         kò sí ìbọ̀wọ̀ fún àgbàgbà mọ́.

     13 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wa ru òkúta;

         àwọn ọmọkùnrin sì ń ṣàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.

     14 Àwọn àgbàgbà ti lọ kúrò ní ẹnu-bodè ìlú;

         àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn.

     15 Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa;

         ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.

     16 Adé ti ṣí kúrò ní orí wa

         ègbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀.

     17 Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa,

         nítorí èyí, ojú wa sì ṣú.

     18 Fún òkè Sioni tí ó ti di ahoro

         lórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri.

 

     19 Ìwọ, Olúwa , jẹ ọba títí láé;

         ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn.

     20 Kí ló dé tí o ń gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà?

         Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́?

     21 Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, Olúwa , kí àwa kí ó le padà;

         mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbàanì,

     22 àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátá

         tí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.